Awọn onimaruwa wọn gun oṣiṣẹ LASTMA nigo loju nitori ọga wọn

Faith Adebọla, Eko

 Ibiiṣẹ ounjẹ oojọ rẹ ni oṣiṣẹ LASTMA yii, Ajibọla Oguntimẹhin, dagbere nile lowurọ Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kọkanlelogun, oṣu Kejila ta a wa yii, amọ ọsibitu ẹkọṣẹ iṣegun lo pada ba ara ẹ lẹyin wakati diẹ to debiiṣẹ ọhun, wọn lawọn alajangbila onikẹkẹ Maruwa kan ni wọn fija pẹẹta pẹlu awọn ẹṣọ LASTMA laaarọ ọjọ naa, wọn binu latari bi wọn ṣe fi pampẹ ofin mu ọkọ ayọkẹlẹ alaga ẹgbẹ wọn to rufin irinna, ni wọn ba gun Ajibọla nigo lẹyinju ẹ l’Ọjọta.

Ba a ṣe gbọ latẹnu Ọga agba ajọ Lagos State Traffic Management Authority (LASTMA), Ọgbẹni Bọlaji Ọrẹagba, o lagbegbe Ọjọta, nijọba ibilẹ Koṣọfẹ, ipinlẹ Eko, niṣẹlẹ naa ti waye.

O ni ọkọ ayọkẹlẹ alaga ẹgbẹ awọn onimaruwa l’Ekoo, Tricycle Owners Association of Nigeria (TOAN), ẹka ti Ọjọta, iyẹn ọkunrin kan tawọn eeyan mọ si ‘Henro’ lo gba ọna ti ko yẹ ko gba laaarọ ọjọ naa, lawọn oṣiṣẹ LASTMA ba mu un pẹlu awakọ rẹ, wọn si wọ ọkọ ti nọmba rẹ jẹ FKJ 161 HB ọhun lọ si teṣan ọlọpaa.

Lẹyin iṣẹju diẹ ti wọn mu ọkọ yii lawọn janduku kan atawọn onikẹkẹ Maruwa ko ara wọn jọ, ti wọn si bẹrẹ si i ṣe akọlu sawọn oṣiṣẹ LASTMA, wọn ni dandan ni kawọn gba ọkọ ọga awọn jade, wọn ni bawo ni oṣiṣẹ LASTMA kan ṣe maa lori laya lati mu ọkọ alaga TOAN, ni wọn ba bẹrẹ ijangbọn buruku pẹlu awọn nnkan ija ti wọn ko dani bii aake, ọbẹ, ada, akufọ igo, apola igi ati oogun abẹnu gọngọ.

Ninu rukerudo to ṣẹlẹ ọhun ni wọn ti figo gun oṣiṣẹ LASTMA, Oguntimẹhin, loju. Wọn tun ṣe awọn ẹṣọ LASTMA mi-in leṣe bo tilẹ jẹ pe awọn kan lara wọn tete fẹsẹ fẹ ẹ, ṣe koju ma ribi, gbogbo ara loogun ẹ.

A gbọ pe wọn ti fun Oguntimẹhin ni itọju pajawiri, amọ ko ti i sẹni to le sọ boya akọlu naa ko ti i ṣakoba fun ẹyinju ọtun rẹ.

Alukoro ileeṣẹ LASTMA, Ọgbẹni Taofiq Adebayọ, ni awọn ti lọọ fẹjọ awọn afurasi ọdaran naa sun ni ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Eria ‘H’ l’Ogudu, wọn si ti bẹrẹ iwadii lori iṣẹlẹ ọhun.

O lawọn ọlọpaa ti n fimu finlẹ lati wa awọn onimaruwa atawọn janduku to wa nidii akọlu yii kan, awọn yoo si ba wọn ṣẹjọ ni kootu, tori wọn gbọdọ jiya iwa abeṣe ti wọn hu naa.

Leave a Reply