Awọn onimọto Oke-Ogun pariwo: Ẹ gba wa lọwọ awọn ọlọpaa ti wọn n lọ wa lọwọ gba

Olu-Theo Omolohun Oke-Ogun.

Niṣe lọrọ di ‘ẹni ori yọ, o d’ile’, lọsan-an  Ọjọbọ, Tọside, ọjọ kẹta, oṣu kọkanla, ọdun yii, lọna marosẹ to lọ siluu Oje-Owode, nijọba lbilẹ Ila-Oorun Ṣaki, ipinlẹ Ọyọ, nigba tawọn awakọ ero atawọn ọlọkada ti wọn n gba ọna naa lọ siluu Ilọrin, ipinlẹ Kwara atawọn ilu mi-in bii Igboho, Igbẹti ati Kiṣi bẹrẹ si i fẹhonu han, ti wọn si n rọjo epe rabandẹ rabandẹ le awọn ọlọpaa lori.

Wọn fẹsun kan awọn ọlọpaa Swift Response Squard (SRS) to n fojoojumọ gbegi dina lọna ọhun pe ole ni wọn n ja, iwa alọnilọwọgba ni wọn n ṣe fawọn, ki i ṣe tori eto aabo to mẹhẹ ni wọn fi wa lọna naa mọ, niṣe ni wọn n re awọn jẹ bii ekute ile, ajẹni-fẹni.

Awọn onimọto atI ọlọkada naa ṣaroye Pe awọn ọlọpaa yii o tiẹ gba tawọn ro, wọn o si ro ti eto aabo to mẹhẹ, ọrọ-aje ti ko dara ati ọwọn gogo ounjẹ ati epo bẹntiroolu ma’wọn lara, niṣe ni wọn tun n pa kun inira awọn.

Awọn tinu n bi naa darukọ awọn ọlọpaa mẹta kan, ASP Ọlanrewaju, Inpẹkitọ Bamidele ati Abdulahi, wọn lawọn ọlọpaa yii atawọn ẹlẹgbẹ wọn ninu ikọ SRS agbegbe naa lo saaba maa n da awọn duro nirona.

Ọkan lara awọn ọmọ ẹgbẹ onimọto ọhun, Ọgbẹni Mutairu Kilanko ṣalaye f’ALAROYE pe, ọkanlerugba Naira din mẹwaa (N210.00) ni wọn n ta jala epo bẹntiroolu nileepo gbogbo l’Oke-Ogun.

O ni lẹyin tawọn ba sanwo fun ẹṣọ alaabo oju popo Road Safety (FRSC),  awọn ẹṣọ to n yẹ idangajia ọkọ wo, VIO, yoo gba tiwọn, bẹẹ lawọn ọlọpaa Operation Burst atawọn ṣọja naa yoo gba tiwọn, awọn ọlọpaa SRS naa yoo duro sawọn lọrun, o ni eelo ni yoo waa pada ṣẹ ku fawọn lati mu rele, bẹẹ awọn ṣi maa tun ọkọ to bajẹ ṣe, awọn yoo si gbọ bukaata.

O ni kijọba bawọn le awọn ‘ajẹlojuonile’ wọnyi kuro lọna kọrọ naa too da bii ti iwọde EndSARS ọjọsi.

Leave a Reply