Awọn ọrẹ mẹta si fipa ba ọmọ ọdun mẹtala lo pọ  

Monisọla Saka

Ko jọ pe awọn ọdọmọkunrin mẹta kan ti awọn ọlọpaa ko darukọ wọn, nitori iwadii to ṣi n lọ lọwọ, yoo bọ ninu ẹsun ifipa ba ni lo pọ ti wọn fi kan wọn. Afaimọ ko ma jẹ pe ẹwọn gbere lo maa gbẹyin ọrọ naa fun wọn. Ọmọ ọdun mẹtala kan lawọn mẹtẹẹta fipa mu lọ si kọrọ kan, ti wọn si fipa ba a lo pọ. Wọn ni nitori pe baba rẹ ṣe awọn lawọn fi gbẹsan iwa naa lara ọmọ baba yii.

Abule kan ti wọn n pe ni Nkpor, ti ko jinna si ilu Onitsha, nipinlẹ Anambra, ni ṣẹlẹ yii ti waye.

 A gbọ pe ile kan naa ni awọn ọmọ yii n gbe pẹlu ọmọbinrin ti wọn fipa ba lo pọ yii. Odo kan ti wọn n pe ni Nkisi, niluu naa, ni wọn mu un lọ, tawọn mẹtẹẹta si fipa ba a lo nibẹ, wọn ni baba rẹ ṣẹ awọn.

Ọmọbinrin yii ṣalaye pe wọn ti kọkọ gba oun loju daadaa, lẹyin naa ni wọn wọ oun lọ si odo yii, ti wọn si ni ki oun bọ aṣọ oun silẹ, ni awọn mẹrẹẹrin ba ba oun laṣepọ lẹyọ-kọọkan.

 A gbọ pe meji ninu awọn ọmọ yii ti jẹwọ pe loootọ ni awọn hu iwa buruku naa, ati pe nitori baba rẹ to ṣẹ awọn lawọn ṣe fiya jẹ ọmọ yii. Wọn ni ki ọmọ naa dariji awọn. Ṣugbọn ikẹta wọn ni oun ko ba ọmọ naa laṣepọ, o ni oun kan n wo wọn nigba ti awọn ẹlẹgbẹ oun n ba a laṣepọ ni. Awọn ẹlẹgbẹ rẹ ti ni irọ lo n pa o, wọn ni oun ni ẹni keji to ba ọmọ naa lo pọ.

 Ileeṣẹ to maa n ri si lilo ọmọ nilokulo ati fifi ọmọ ṣowo ẹru, iyẹn National Agency for Prohibition of Trafficking in persons, pẹlu ifọwsowọpọ awọn fijilante ni wọn mu mẹta ninu awọn ọmọkunrin to huwa ibajẹ naa, nigba ti ẹni kẹrin wọn sa lọ nigba ti wọn wa a lọ si adugbo to n gbe.

Nigba to n fidi iṣẹlẹ naa to awọn oniroyin leti, Chidimma Ikeanyionwu, to sọrọ naa lorukọ Kọmiṣanna fọrọ awọn obinrin ati ọrọ afẹ nipinlẹ naa, Ify Obiano, sọ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ keji, oṣu Kọkanla yii, pe ọwọ ti tẹ mẹta ninu wọn, awọn si ti fa wọn le ọlọpaa lọwọ fun iwadii to ba yẹ.  

Leave a Reply