Stephen Ajagbe, Ilorin
Ọmọ Sẹriki Fulani tilu Igangan, nipinlẹ Ọyọ, Saliu Ibrahim, ti ni awọn ọta baba oun tinu wọn ko dun si bo ṣe jẹ oye naa lo n ṣatilẹyin fun ajijangbara nni, Sunday Adeyẹmọ, tawọn eeyan mọ si Sunday Igboho, lati kọ lu wọn.
O ni ile awọn nikan ni Sunday atawọn eeyan rẹ waa kọ lu, wọn si fi awọn Fulani kan silẹ laarin ilu naa ti wọn si n gbebẹ titi di akoko yii.
Saliu ni ko si oootọ ninu ẹsun ti wọn fi n kan baba oun pe o n ṣe agbodegba fawọn ajinigbe, nitori pe gẹgẹ bii Sẹriki, oun gan-an lo maa n yanju aawọ to ba su yọ laarin awọn agbẹ ati darandaran, paapaa ti maaluu ba jẹ oko.
O ni oun atawọn ẹgbọn oun, ilu Igangan ni wọn bi awọn si, ko si si wahala kankan laarin awọn atawọn araalu latigba tawọn ti n gbebẹ, afigba tawọn bẹrẹ si i gbọ nipa iṣẹlẹ ijinigbe.
Ọkunrin naa ni eeyan mẹta ni wọn ji gbe niluu naa; Wasiu, Alhaji Ọlọṣunde ati Mọsuru Aderoju. O ni gbogbo awọn eeyan naa lo ṣi wa laye, wọn le pe wọn ki wọn ṣewadi nipa ẹni to ba wọn ṣe idunaadura nipa owo tawọn ajinigbe gba lọwọ wọn.
O pe awọn to n pariwo kiri pe baba oun n ṣe agbodegba fawọn ajinigbe lati jade sita ki wọn waa sọ ọ. O ni Dokita Aborode nikan lo ti ku laarin awọn ti wọn kọlu niluu Igangan.
“Awọn to n pariwo gan-an nipa iku Dokita Aborode ko sun mọ ọn to awa yii, awa niku rẹ dun ju. Emi ati ẹ jọ ṣe ipolongo ibo ni nigba to fẹẹ dije fun ile aṣoju-ṣofin lẹgbẹ Accord, koda nigba to tun lọ ADC a jọ ṣe ipolongo ni. Nigba to fẹẹ pada si PDP, o pe mi, o si ṣeleri pe kawa Fulani ni suuru, o ni oun ṣi maa ṣe nnkan fun wa.”
O ni Dokita Aborode gan-an ko kọyan awọn Fulani kere, nitori pe wọn maa n ran oun lọwọ ninu oko oun.
O ni lati fi imoore han, Aborode ra iyọ, o si pin in fun awọn Fulani to n ran an lọwọ, oun gan-an lo fun lowo lati lọọ ra a fun wọn.
“Ẹnikan to n jẹ Hassan to jẹ Bororo gba ninu iyọ naa. Ọjọ ti wọn da Dokita Aborode dubulẹ ti wọn fẹẹ pa a, ariwo to n pa ni pe to ba jẹ owo ni wọn n fẹ koun fun wọn, ki wọn jọwo, ki wọn ma pa oun. Awọn to pa a gan-an a o mọ wọn.
“Ọdun 2006 ti mo pari OND mi ni mo mọ Aborode, nigba naa, ileeṣẹ Larfarge, ni Ṣhagamu, ni wọn ti n ṣiṣẹ, baba rẹ lo fun mi ni lẹta pe ki n lọọ ba a nibẹ ki n le ṣiṣẹ.”
O ni ko sigba kankan ti Aborode sọ fun Seriki pe maaluu jẹ oko oun, to ba fẹẹ ṣe bẹẹ, oun lo maa kọkọ sọ fun.
“Awọn to jẹ ọmọ ilu Igangan, ti wọn jẹ Taye-Kẹhinde, ti wọn n ji maaluu gbe, ti wọn tun n pada ji eeyan, awa atawọn ọlọpaa la jọ ṣiṣẹ ta a fi mu wọn, wọn wa ni ọgba ẹwọn Agodi bi a ti ṣe n sọrọ yii. Ṣe o ṣee ṣe fun ẹni to n mu awọn ajinigbe lati maa ṣe agbodegba fun wọn?
“Awọn to jẹ ọta baba mi lo n ti Sunday Igboho lẹyin lati kọ lu u. Ṣe ẹ mọ pe ko si ẹya ti ki i si awọn to n binu ara wọn. Lati ọjọ ti Alaafin ti fi baba mi jẹ Sẹriki Fulani Igangan ni wahala ti bẹrẹ. Awọn kan ro o pe awọn lo yẹ ko jẹ oye naa. Titi de ori adari Mayetti Allah, ija ṣi wa lori ẹ, koda ẹjọ n lọ ni kootu.
“Ohun to n fa wahala ni Mayetti Allah ni pe ẹni to ba maa jẹ alaga gbọdọ kawe ki o ni diploma, ṣugbọn ẹni ti wọn fi jẹ e ko ni iwe-ẹri pamari lọwọ.”