Faith Adebọla, Eko
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko ni ọwọ ti ba awọn afurasi kan, iwadii si ti n lọ lọwọ bayii lori bawọn kan ṣe ṣawari ajaalẹ ti wọn lawọn gbọmọgbọmọ n lo lagbegbe Orile-Iganmu, nipinlẹ Eko.
Ọgbẹni Olumuyiwa Adejọbi, Alukoro ọlọpaa Eko, ṣalaye fun ALAROYE lori foonu nipa iṣẹlẹ naa pe Kọmiṣanna ọlọpaa, Hakeem Odumosu, ti gbọ nipa iṣẹlẹ naa, o si ti fa iwadii ọrọ ọhun le ẹka ileeṣẹ ọtẹlẹmuyẹ to wa ni Panti, ni Yaba, lọwọ lati tọpinpin rẹ.
O ni ọkunrin kan tọwọ ba ti wọn pe ni Kayọde, ẹni aadọta ọdun, atawọn mi-in, ti wa lakata awọn ọtẹlẹmuyẹ. Kayọde yii ni wọn fẹsun kan pe wọn ba ori ati ọkan eeyan lọwọ ẹ lasiko ti wọn fi fa a le awọn ọlọpaa lọwọ.
Adejọbi ni, ‘Ṣe ẹ mọ, iru awọn ẹjọ bayii maa n gba iwadii afẹsọ-ṣe gidi, iṣẹ ifimufinlẹ lati mọ hulẹhulẹ bi kinni naa ti jẹ gan-an, ṣugbọn pẹlu awọn tọwọ ti ba, ti wọn si ti n ba awọn agbofinro sọrọ, o daju pe a maa ri okodoro bọrọ naa ti jẹ.’
Nnkan bii iyalẹta Ọjọruu, Tọsidee, to kọja yii, lawọn araadugbo kan lagbegbe Orile-Iganmu fura si bi ọkunrin kan tẹnikan ko ti i mọ orukọ rẹ ṣe n rin kọsẹ kọsẹ laduugbo naa, n ni wọn ba bẹrẹ si i sọ ọ.
Gẹgẹ baa ṣe gbọ, wọn lẹnikan ko mọgba ti ọkunrin naa ṣadeede poora bii iso, eyi lo si tubọ ru ifura awọn ti wọn ti n ṣakiyesi ẹ tẹlẹ soke. Bẹẹ ni wọn lawọn kan n bẹru ko ma lọọ jẹ pe adigunjale lọkunrin ti wọn lo de fila dudu sori ọhun, wọn ni boya niṣe lo lọọ lugọ sibi kan lati ṣe wọn ni ṣuta tọjọ ba pofiri.
Ọrọ yii ni wọn lo mu ki wọn ke si awọn ẹṣọ OPC to wa lagbegbe naa. Awọn OPC yii ni wọn bẹrẹ si i fọ gbogbo adugbo.
Ẹnu wiwa ti wọn n wa a yii ni wọn ri ami kan ati awọn ipasẹ kan, bi wọn si ti tọpinpin ami ọhun, ko pẹ rara ti wọn fi hulẹ kan kọnkere pẹlẹbẹ (slab) kan ti wọn fi bo oju iho tawọn olubi ẹda yii n gba wọnu ajaalẹ to dudu kirikiri naa.
Wọn lawọn OPC yii rọ wọnu ajaalẹ ọhun, ṣugbọn o jin gan-an, o si gun debii pe lati Orile-Iganmu, agbegbe Mile 2 lo jade si.
Wọn ni bi wọn ṣe n tọpa ajaalẹ naa lọ ni wọn bẹrẹ si i kan awọn aṣọ ileewe oriṣiiriṣii, tọkunrin tobinrin, bata atawọn nnkan ẹṣọ ara mi-in. Wọn tun ri awọn ẹya ara eeyan to ti jẹra, awọn mi-in ti gbẹ keegun. Wọn ri ẹrọ amunawa (jẹnẹratọ), ẹrọ amuletutu.
Ko pẹ ni wọn ri ọkunrin ti wọn fura si tẹlẹ pe gbọmọgbọmọ ni, wọn lo gbe ori eeyan dani, ti ọkunrin mi-in si tun tẹle e, ibi abayọ ajaalẹ ọhun to jade si Mile-2 ni wọn gba wọle. Bi wọn ṣe ri awọn OPC ni wọn fere ge e, ṣugbọn wọn ni ko rọrun fun wọn lati sare pupọ tori tooro ni iho ajaalẹ naa, n lọwọ ba tẹ wọn.
Igba ti wọn wọ awọn afurasi mejeeji jade, tawọn ọdọ ati aladuugbo foju kan wọn, niṣe ni wọn bo wọn bi i eeṣu, wọn si fi lilu ba tiwọn jẹ. Kia lawọn ti wọn da ọkunrin ti wọn ti kọkọ ri tẹlẹ naa mọ fibinu fi taya kọ ọ lọrun, wọn bu bẹntiroolu si, ni wọn ba dana sun un rau.
Ọpẹlọpẹ awọn ọlọpaa to sare debi iṣẹlẹ naa ni ko jẹ ki wọn dana sun ọkunrin keji, ti wọn fi mu un lọ sagọọ wọn.
Alukoro ọlọpaa Eko ni wọn ti paṣẹ fawọn ọlọpaa Area C lati tubọ ro eto aabo agbegbe naa lagbara.