Stephen Ajagbe, Ilọrin
Awọn oṣiṣẹ panpana ti ri oku Okechukwu Orwabo, ọkan lara awọn eeyan mẹta to ko sodo lasiko ti afara kan da wo ni alẹ ọjọ Abamẹta, Satide, ni agbegbe Oko-Erin, niluu Ilọrin
ALAROYE gbọ pe arọọda ojo to rọ mọju ọjọ Sannde lo wo apa kan lara afara naa, eyi ni wọn lo fa ijamba ọhun.
Awọn meji la gbọ pe ori ko yọ ninu ijamba naa ninu awọn marun-un to wa ninu ọkọ ọhun, mẹta ninu wọn ni omi gbe lọ.
Alukoro ileeṣẹ panpana nipinlẹ Kwara, Ọgbẹni Hassan Hakeem Adekunle, kede ọrọ naa ninu atẹjade kan lọjọ Aiku, Sannde, ọsẹ yii.
Adekunle ni awọn meji; Chuben Orwabo ati Chibike Orwabo ni wọn ṣi n wa.
Lasiko to n ṣalaye bi ijamba naa ṣe ṣẹlẹ, Adekunle ni ni nnkan bii aago mẹwaa aabọ alẹ ọjọ Satide ni ileeṣẹ ọhun gba ipe pajawiri pe ọkọ ayọkẹlẹ kan ha sinu ọgbara ojo lori afara naa. O ni ọkan lara awọn ero inu ọkọ naa lo kọkọ jade lati wo ibi ti omi naa mu mọto wọn de, kiyẹn si too mọ ohun to n ṣẹlẹ, apa ibi to duro si naa wo lulẹ, o si re bọ sinu odo.
O ni oju ẹsẹ ni awọn meji mi-in tun jade lati doola ẹni akọkọ, bi omi ṣe tun wọ awọn naa sinu odo niyẹn.
O ṣalaye pe ọna Coca-cola ni awọn ti pada ri oku Okechukwu, awọn ṣi n tẹsiwaju lati wa awọn meji yooku.
Nigba ti akọroyin wa de ibi iṣẹlẹ naa, awọn oṣiṣẹ panapana ṣi wa nibẹ ti wọn n wa oku awọn ti wọn ko ti i ri kiri ninu odo.