Ọrẹoluwa Adedeji
Lati sa fun ijiya to le tidi ofin pe ẹnikẹni to ba ni i lọkan lati dupo oṣelu kan tabi omi-in gbọdọ kọwe fipo wọn silẹ lo mu ki Alaga ẹgbẹ oṣelu APC ti wọn ṣẹṣẹ dibo yan, Abdullahi Adamu to n ṣoju agbegbe rẹ nipinlẹ Nasarawa ati aṣofin mi-in to wa lati ipinlẹ Borno, Sẹnetọ Abubakar Kyari, kọwe fipo wọn silẹ gẹgẹ bii ọmọ ileegbimọ aṣofin agba.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, ni Olori ile naa, Ahmad Lawan ka lẹta tawọn eeyan naa kọ lọtọọtọ lati fi ipinnu wọn han pe awọn ko ṣoju awọn eeyan awọn nile naa gẹgẹ bii aṣofin mọ.
Ko too di pe wọn yan Adamu gẹgẹ bii alaga gbogbogboo fun ẹgbẹ APC, ọkunrin naa ni alaga igbimọ to n mojuto eto ọgbin ati igberiko.