Faith Adebọla, Eko
“Ẹ wo o, lati oṣu kin-in-ni, ọdun 2019, lemi ti n digunjale, mi o si le ṣiwọ. Ti mi o ba gbe ibọn dani gan-an, ti mo ba ṣaa ti ri ina tọṣilaiti (touchlight), mo maa pari iṣẹ lai sewu.
“Ẹyin ọlọpaa, ẹ ma wulẹ da mi pada sọgba ẹwọn, tori ẹ kan fẹẹ maa fakoko ṣofo ni, tori ti mo ba pada de, ma a tun lọọ gboro si i ni. Afi tẹẹ ba pa mi danu nikan lawọn ọmọ Naijiria le bọ lọwọ mi.”
Eyi lawọn ọrọ ti ọdaju afurasi adigunjale kan, Adeniyi Ajayi, ẹni ọdun mẹtadinlọgbọn, n sọ ni teṣan SARS, nigba tọwọ ikọ ọlọpaa to n gbogun ti iwa idigunjale tẹ ẹ l’Ọjọbọ, Wẹsidee,ọsẹ kọja yii ninu otẹẹli kan lagbegbe 7-Up, n’Ijọra Badiya.
AKEDE AGBAYE gbọ pe o pẹ ti Adeniyiti maa n paara ọgba ẹwọn. Aipẹ yii ni wọn lo ṣẹṣẹ tẹwọn kan de latari ẹsun idigunjale ti wọn lo jẹbi rẹ nigba kan, ṣugbọn bo ṣe tẹwọn ọhun de lo tun pada sidii iṣẹ buruku rẹ.
Wọn ni bawọn eeyan ṣe gbọ pe ọwọ tun ti tẹ jagunlabi lawọn eeyan bii mẹjọ kan ti ya bo teṣan ọlọpaa SARS, ni Panti, tawọn obinrin si fẹsun kan ọkunrin naa pe yatọ si iwa idigunjale, o tun maa n fipa ba awọn lo pọ.
Meji ninu awọn obinrin to ti ṣe kinni ọhun fun royin pe lọjọ kẹrindinlogun, oṣu kẹfa, to kọja yii, afurasi naa waa digun ja ileeṣẹ tawọn ti n ṣiṣẹ lagbegbe Sabo lole, niṣoju awọn oṣiṣẹ to ku lo ti fipa ba awọn sun lọsan-an gangan.
Eyi ni wọn lo mu kawọn ọlọpaa wọ ọ jade lahaamọ to wa lati fidi otitọ mulẹ.
Nigba ti Adeniyi maa fesi, o ni ko sirọ ninu ẹsun ti wọn fi kan oun, ṣugbọn ki i ṣe pe oun kan maa n ṣadeede ba awọn obinrin sun o, igba tawọn ọkọ wọn ko ba ri owo toun beere fun loun maa n fi iyawo tabi ọmọọdọ wọn di i.
O loun ki i paayan ni toun, afi tawọn toun fẹẹ ja lole ko ba kọpureeti tabi tawọn obinrin wọn ba fẹẹ ṣagidi lo le mu ki wọn tọ iku la.
Afurasi naa tun jẹwọ pe lọpọ igba, awọn eeyan ki i mọ pe oun nikan ṣoṣo loun n ṣe opureṣan, o ni niṣe loun maa n dibọn, toun maa n paṣẹ bii pe awọn bọis oun wa nita, kẹru le ba awọn toun fẹẹ ja lole, ṣugbọn oun nikan loun maa n da iṣẹ ṣe.
Afaimọ ko ma jẹ ibi ti Adeniyi fẹ kọrọ ọun ja si naa lo maa ja si, tori Alukoro ọlọpaa ipinlẹ Eko, Bala Elkana, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ ti sọ pe kete tawọn ba ti pari iwadii to n lọ lọwọ lawọn maa taari afurasi naa sile-ẹjọ, ki wọn le da sẹria to tọ fun un.