Ọlawale Ajao, Ibadan
Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ ti gbe meje ninu awọn afurasi ọdaran ti wọn dana sun ile ati ọpọlọpọ ṣọọbu ni Ṣáṣá, n’Ibadan, lọ sí kootu, Onídàájọ I.O. Osho sí ti pàṣẹ pé ki wọn lọọ fi gbogbo won pamọ sí àhámọ́ ọgbà ẹwọn Abolongo to wa nílùú Ọyọ.
Orúkọ awọn olujẹjọ mejeeje ọhun ni Tajudeen Ọladunni, ẹni àádọ́ta (50); Saburi Lawal, ẹni ọdun mẹtadinlogoji (37); Ojo Joshua, ẹni ọdun mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25); Adekunle Ọlanrewaju, ẹni ọdun mejidinlogoji (38); Ọlagunju James, ẹni ọdun mẹrinlelogun (24); Rasaq Yahya, ẹni ọdun mejilelọgbọn (32) ati ọmọkunrin ẹni ogún (20) ọdun kan to n jẹ Ọlaide Ọlawuyi.
Ẹsun mẹfa ọtọọtọ to ni i ṣẹ pẹlu iwa ọdaran ni wọn ká sì wọn lẹsẹ ni kootu Majisireeti to wa ni Iyaganku, n’Ibadan.
Tẹ̣ o ba gbagbe, lọjọ kejìlá oṣù kejì, ọdun yii, ni rogbodiyan bẹ silẹ ninu ọja Ṣáṣá, lẹyin ti Hausa kan lu ọmọ Yorùbá kan to n jẹ Adéọlá Shakiru lóòka pa nitori to n gbiyanju lati la Hausa náa pelu alaboyun kan to n bá já nija.
Ninu awijare ẹ, agbẹjọro ileeṣẹ ọlọpaa, Rìpẹ́tọ̀ Fólúkẹ́ Ọladoṣu, ṣalaye pe awọn olujẹjọ yii, pẹlu awọn mi-in ti ọwọ awọn agbofinro kò ti i tẹ ni wọn dana sun awọn ile ati ṣọọbu to jona ni Ṣáṣá lasiko laasigbo to tìdí iku Shakiru yọ.
Ọkan ninu awọn to kagbako ìwà ọdaju àwọn olubi èèyàn yìí gẹgẹ bí Amofin Ọladoṣu ṣe fìdí è múlẹ siwaju ni Alhaji Ibrahim Adelabu, ẹni ti ALAROYE gbe iroyin jade nipa ẹ ni kete ti iṣẹlẹ naa waye.
Lẹyin ti wọn ka awọn ẹsun ọhun sí awọn olujẹjọ létí, adajọ kò faaye silẹ fún wọn láti wí awijare wọn tó fi pàṣẹ pé kí wọn lọọ fi wọn pamọ́ sí àhámọ́ ọgbà ẹwọn titi digba ti DPP, ìyẹn ẹka ileeṣẹ eto idajọ ipinlẹ Ọyọ yóò fi gba ilé-ẹjọ́ naa nimọran lori ọna ti wọn yóò gbé igbẹjọ ọhun gbà.
Onídàájọ Ọshọ waa sun ijokoo mi-in lori igbẹjọ naa sí ọjọ kọkànlá, oṣù karun-un, ọdun 2021 yii.