Awọn to ji Aafaa Giwa gbe n’llọrin yari, wọn ni miliọnu mẹrin kere fawọn gẹgẹ bii owo itusilẹ 

Ibrahim Alagunmu, Ilorin

Adura lo ku ti awọn mọlẹbi ọga ileewe aladaani kan, Aafaa Giwa, ti wọn ji gbe lagbegbe Wáráh, nijọba ibilẹ Ìwọ-Oòrùn Ilọrin (West), lopin ọṣẹ to kọja n gba bayii pe k’Ọlọrun ko si awọn ajinigbe naa ninu, ki wọn le wo awọn ṣe pẹlu owo tuulutuulu ti wọn lawọn feẹ gba ki wọn too le tu ọkunrin naa silẹ. Nitori niṣe lawọn ajinigbe ọhun yari pe awọn ko le gba miliọnu mẹrin ti mọlẹbi aafaa naa fẹẹ san gẹgẹ bii owo itusilẹ. Wọn ni bi wọn ko ba pese miliọnu mẹẹẹdogun Naira, a jẹ pe wọn ko fẹẹ ri eeyan wọn ọhun gba ni, nitori ko ni i kuro lakata awọn bi owo na ko ba pe perepere.

ALAROYE gbọ pe ọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kọkanka yii, ni wọn ji Aafaa Giwa gbe lagbegbe Wáráh, niluu Ilọrin. Lẹyin ti wọn ji i gbe tan ni wọn pe mọlẹbi rẹ, ti wọn si n beere fun miliọnu mẹẹẹdogun Naira.

Ọkan lara awọn olori agbegbe naa to fidi iṣẹlẹ naa mulẹ, Alaaji Abdulkadir Onílé, sọ pe loootọ ni awọn ajinigbe ji Aafaa Giwa gbe, ti wọn si n beere fun miliọnu mẹẹẹdogun Naira, ṣugbọn gbogbo adugbo gbiyanju agbara wọn lati ṣa miliọnu mẹrin jọ, ṣugbọn awọn ajinigbe naa kọ owo ọhun silẹ, wọn ni owo naa kere pupọ, awọn ko le gba a. O tẹsiwaju pe idunaadura ṣi n tẹsiwaju, bẹẹ ni Giwa ṣi n bẹ lakata awọn ajinigbe titi di ba a ṣe n ṣọ yii.

Alaaji Abdulkadir ni nnkan ẹyọ kan tawọn n ṣe bayii ni gbigba adura kikankikan, ki Giwa le dari wale layọ ati alaafia.

Ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Kwara, naa fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ, wọn ni gbogbo awọn ẹsun ijinigbe yii lawọn yoo yanju laipẹ.

Leave a Reply