‘‘Awọn to ji wa gbe fi oku eeyan to ti n jẹra han wa ninu igbo ti wọn ko wa lọ’’

Faith Adebọla

Aja to rele ẹkun to bọ, ka ki i ku ewu ni. Oniruuru iriri buruku to ṣẹlẹ sawọn eeyan tawọn janduku ajinigbe afẹmiṣofo n ji gbe ninu igbo ni Olori ijọ eleto, iyẹn Ṣọọṣi Mẹtọdiisi (Methodist) ni Naijiria, Ẹni-ọwọ Samuel Kanu-Uche, ṣalaye nigba ti wọn tu u silẹ nigbekun awọn ajinigbe ọhun lọjọ Aje, Mọnde, to kọja yii.
Nigba tọkunrin ẹni aadọrin ọdun naa n sọ ohun toju ẹ ri fawọn oniroyin l’Ekoo, lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Karun-un yii, o ni miliọnu lọna ọgọrun-un Naira (N100 million) lawọn ajinigbe naa gba ki wọn too tu oun silẹ.
“Nnkan bii aago mẹrin irọlẹ ni, lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu Karun-un, loju ọna marosẹ Enugu si Port Harcourt, nijọba ibilẹ Umunneochi, nipinlẹ Abia. Nnkan bii aago meji ọsan la ti gbera, tori ka le ba baaluu ta a fẹẹ wọ, emi ati ẹni keji mi, Ojiṣẹ Ọlọrun Rẹfurẹndi Abidemi Shittu, ati Biṣọọpu ti Owerri, Rẹfurẹndi agba, Dennis Mark. A o fura rara pe awọn ajinigbe le wa lọna yẹn.
“O ku diẹ ka wọ Ileru, ni Abia, niṣe ni wọn jade lojiji si wa ninu igbo, wọn pin ara wọn si mẹta, awọn kan rọ jade lẹyin wa, awọn kan wa niwaju wa, awọn ti wọn wa laarin ni wọn waa ba wa, wọn yinbọn lu ọkọ wa, wọn si ji wa gbe. Ṣugbọn awakọ mọto naa ati agbẹnusọ ijọ to wa pẹlu wa raaye sa lọ.
“Ninu igbo, wọn fiya jẹ wa, wọn lu wa. Wọn gba mi loju ni agbamọgi, oju mi bẹ ẹjẹ, mọ kigbe pẹlu bi ẹjẹ ṣe rin ankaṣifi mi gbindin, awọn eeyankeeyan yii o tiẹ wo ibẹ lẹẹmeji, wọn kan paṣẹ fun wa pe ka maa niṣo ni.
“Mẹjọ ni wọn, awọn bọisi ẹya Fulani ni wọn, wọn lawọn n ba ijọba Naijiria ja. Ọkan ninu wọn gbọ ede oyinbo taa-taa-taa, ṣugbọn ede Fulfilde tawọn Fulani n sọ lawọn yooku gbọ. Wọn tiẹ sọ pe tọwọ awọn ba le tẹ Buhari, niṣe lawọn maa jẹ ẹ ni tutu, tawọn maa run un lẹnu ṣamuṣamu, wọn lo ja awọn kulẹ, wọn lohun tawọn ni ko ṣe kọ lo n ṣe yii.
“Nigba ti a ti rin to kilomita mẹẹẹdogun ninu igbo kijikiji, ni nnkan bii aago mọkanla alẹ, wọn ni ka jọ dunaa-dura, wọn ni ki ọkọọkan awa mẹtẹẹta san aadọta miliọnu Naira, eyi ti aropọ rẹ jẹ aadọjọ miliọnu Naira (N150 million). Nigba to ya, wọn ni awọn maa gba ọgọrun-un miliọnu ti ko ja leti.
“Mo pe iyawo mi lori aago, mo ba awọn adari ṣọọṣi sọrọ pe ki wọn wa owo yẹn lọnakọna, tori nigba ta a fẹẹ bẹ wọn boya wọn le din owo naa ku diẹ si i, niṣe ni wọn doju ibọn kọ wa, wọn lawọn maa pa wa danu ni. Olori wọn ko ju ẹni ọdun marundinlogoji lọ. Wọn la o gbọdọ sọ nnkan kan fawọn DSS, tabi ṣọja tabi awọn agbofinro kankan, afi ta a ba fẹẹ fiku ṣefa jẹ.
‘‘Wọn fi koto giriwo kan han wa lọọọkan, wọn leeyan meje lawọn ti pa sinu ẹ, wọn lawọn dumbu wọn ni, awa naa si n gbooorun buruku to n fẹ wa lati ibẹ.
‘‘Olori wọn ni inu baagi Ghana-must-go marun-un ni ki wọn di owo naa si, o tun sọ pe Eko lo ku tawọn ti fẹẹ ṣakọlu bayii, awọn si ti pari eto lori ẹ.
Afi kawọn olori wa tete wa nnkan ṣe ki rẹrẹ too bẹrẹ si i run, tori iṣoro yii, iṣoro aisi olori to to tan ni. Ijọ wa lo dawo ti wọn fi tu wa silẹ, ijọba ko da si i. Awa o ni kanga epo rọbi, ẹnikẹni to ba ṣakọlu si ijọ lati fi gba owo, owo ẹjẹ ni tọhun gba. Ileeṣẹ ologun ilẹ wa mọ nipa iwa ijinigbe yii, ọwọ wọn o mọ.”
Bẹẹ ni baba agba naa royin ohun toju ẹ ri.

Leave a Reply