Ọlawale Ajao, Ibadan
Meje ninu awọn to n jijangbara fun idasilẹ orileede Oodua ti wọn kọ lu ileeṣẹ redio Amuludun, to wa ni Mọniya, niluu Ibadan, ipinlẹ Ọyọ, ti dero ahamọ ọgba ẹwọn.
Lọjọ Aje, Mọnde, ọjọ kọkandinlogun, oṣu Kẹfa, ọdun 2023 yii, ni CP Adebọwale Williams ti i ṣe ọga ọlọpaa ipinlẹ Ọyọ wọ wọn lọ sile-ẹjọ Majisreeti to wa ni Iyaganku, niluu Ibadan.
Orukọ awọn mejeeje ti wọn wọ lọ sile-ẹjọ ni Noah Atoyebi, Adeleke Gbenga, Abdulganiyu Mustapha, Bashiru Kẹhinde, Ifagbọla Elijah, Ọladapọ Ajani ati Rasheed Jimoh.
Ẹsun mẹrin ọtọọtọ to da lori idigunjale, iditẹgbajọba, ati igbimọ-pọ lati idigunjale ni wọn fi kan wọn.
Adajọ kootu ọhun, Onidaajọ P.O Adetuyi, ko gba ipẹ awọn olujẹjọ yii, niṣe lo ni ki wọn lọọ ti wọn mọ ọgba ẹwọn Abolongo, niluu Ọyọ.
Agbẹjọro eyi to n jẹ Adeleke Gbenga ninu awọn olujẹjọ, Amofin Abiọdun Adeleke, rọ ile-ẹjọ lati gba beeli onibaara rẹ nitori tọkunrin naa nilo itọju nileewosan, eyi ti agbefọba, Fọlakẹ Ewe, ko ta ko.
Nigba to n sun ẹjọ si ọjọ kẹtala, oṣu Kẹsan-an, ọdun yii, Onidaajọ Adetuyi sọ pe oun yoo fi ọrọ ẹjọ yii to wọn leti lẹka to n gba awọn ile-ẹjọ nimọran fun amọran to yẹ lori ẹjọ naa.
Tẹ o ba gbagbe, lọjọ kejidinlọgbọn, oṣu Karun-un, ọdun 2023 yii, lawọn kan ya wọ ileeṣẹ redio Amuludun to wa ni Mọniya, ti wọn ko si jẹ ki wọn raaye gbohun safẹfẹ fun bii wakati kan ko too di pe awọn oṣiṣẹ eleto aabo pada kapa wọn.