Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ.
Gomina ipinlẹ Ondo, Arakunrin Rotimi Akeredolu, ti ranṣẹ ikilọ si gbogbo awọn ti wọn n jijagbara, ti wọn si n pe fun idasilẹ orilẹ-ede Oodua lati lọọ wa nnkan mi-in ṣe, o ni ala ti ko le ṣẹ ni ọrọ Yoruba Nation ti wọn ni awọn n ja fun.
Alaga awọn gomina lẹkun Guusu Iwọ-Oorun orilẹ-ede yii lo sọrọ yii lasiko ti wọn n ṣe ifilọlẹ kinni ti wọn maa n lẹ mọya (sticker) ti wọn ṣe fun imurasilẹ ayẹyẹ ọdọọdun ti wọn maa n ṣe lati bu ọla fun awọn jagunjagun Naijiria to ti ku ṣoju ogun.
Aketi ni ko si eyikeyii ninu awọn ipinlẹ to wa nilẹ Yoruba ti yoo faaye gba erongba awọn alakatakiti wọnyi lati wa si imuṣẹ nitori ẹjẹ ọpọ awọn akọni ti wọn ti ta silẹ gẹgẹ bii etutu fun ifẹṣẹmulẹ alaafia ati iṣọkan Naijiria.
O ni orilẹ-ede Naijiria ṣe pataki pupọ si awọn gomina ilẹ Yoruba ju ki awọn waa faaye gba igbakugba ati aṣẹ onikondo tawọn ẹgbẹ to n ja fun ominira ilẹ Biafra (IPOB) n pa, ninu eyi ti wọn ti n fipa mu awọn eeyan lati jokoo pa sile. Iru eyi lo ni ko ni i ṣee ṣe rara nibikibi nilẹ Yoruba.
Arakunrin ni loootọ lofin Naijiria fun awọn eeyan lanfaani lati fẹhonu han tabi ki wọn jijagbara fun nnkan ti wọn ba n fẹ, amọ niwọn igba tawọn agbofinro ba ti kede iru igbesẹ bẹẹ bii eyi to lodi sofin, o ṣee ki wọn fi pampẹ ofin gbe ẹni to ba lọwọ ninu rẹ, ki wọn si foju rẹ wina ofin.
Arakunrin ni ohun to yẹ ko jẹ awọn ọmọ orilẹ-ede yii logun ju lọ lasiko yii ni bi wọn yoo ṣe maa pin ipo agbara iṣakoso Naijiria ni ẹlẹkunjẹkun titi ti yoo fi kari.
O ni ki i ṣe asiko ti ọpọn oriire ti fẹẹ sun kan awọn eeyan ilẹ kaaarọ-oo-jiire lo yẹ kawọn ọta ilọsiwaju kan ṣẹṣẹ waa maa figbe Yoruba Neṣan bọnu.
Oun atawọn gomina ẹgbẹ rẹ yooku lo ni awọn ko ṣetan lati ṣatilẹyin fawọn ajijagbara naa nitori pe gbogbo ipa to wa nikaawọ awọn lawọn ti sa fun idagbasoke ati ire Naijiria.
Akeredolu ni gbaagbaagba lawọn wa lẹyin awọn ẹṣọ aabo lati ka awọn ọta ilọsiwaju wọnyi lọwọ ko, ati pe oun ti yoo jẹ koriya fawọn jagunjagun to ti fi ẹmi wọn lelẹ fun alaafia ati iṣọkan Naijiria lawọn wa fun lọwọlọwọ.
Gomina ọhun fi imọriri rẹ han fun iṣẹ takuntakun tawọn ọmọ ologun naa ti ṣe, bẹẹ lo ni iṣejọba oun ti ṣetan lati maa ṣatilẹyin fun gbogbo ẹgbẹ to ba ti n dìde lati ran ẹbi awọn to ti ja fitafita fun ilọsiwaju Naijiria lọwọ.