Awọn to sọ pe mo ti ku, irọ ni wọn n pa-Tinubu

Faith Adebọla

Ṣe bi ogun ẹni ba da ni loju, a fi maa n gba ori ni. Eyi gan-an lo ṣẹ mọ oludije funpo aarẹ ninu ẹgbẹ oṣelu APC, Aṣiwaju Bọla Tinubu, lara pẹlu bi baba naa ṣe gbe aworan ibi to ti n wa kẹkẹ sori ikanni abẹyẹfo, Twita (Twitter), rẹ, leyii to fi n sọ fun gbogbo awọn ti wọn n sọ pe ara baba naa ko ya, ti awọn mi-in si n sọ pe abi o ti ku ni pe ko si ohun to ṣe oun.

Labẹ fidio naa ni Tinubu kọ awọn ọrọ kan si pe ‘‘Ọpọ awọn eeyan kan sọ pe mo ti ku, awọn kan sọ pe mo ti jawọ, pe n ko dije dupo aarẹ mọ.

‘‘Ṣugbọn o, ko ri bẹẹ rara. Okodoro ọrọ to wa nibẹ ni pe koko ni ara mi le bii ara ọta, ko sohun to ṣe ilera mi paapaa, mo si ti ṢETAN lati sin orileede mi lati ọjọ akọkọ.’’

Bi Tinubu ṣe kọ ọ si abẹ fidio na niyi.

Leave a Reply