Awọn tọọgi Akeredolu ati ti Jẹgẹdẹ kọju ija sira wọn ni Ọba-Akoko

Oluṣẹyẹ Iyiade Akurẹ

 Niṣe lọrọ di bo o lọ o yago niluu Ọba-Akoko, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Akoko, nipinlẹ Ondo, l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, nigba ti awọn tọọgi ẹgbẹ oṣelu APC ati PDP kọju ija sira wọn. Bẹẹ ni wọn ba mọto meji jẹ, gbogbo gilaasi ọkọ naa lo run womuwomu.

ALAROYE gbọ pe wahala naa waye lasiko ipolongo ibo Akeredolu to jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu APC ati Eyitayọ Jẹgẹdẹ toun jẹ ọmọ ẹgbẹ PDP. Lasiko ti wọn pade laọn tọọgi ẹgbẹ oṣelu mejeeji kọju ija sira wọn.

Akọwe ipolongo iroyin fun Jẹgẹdẹ, Fasua Samuel, to ṣalaye pe eto polongo ibo lawọn n ṣe lọwọ ti Gomina Rotimi Akeredolu atawọn ọmọ lẹyin rẹ kan fi kọwọọrin de.

O ni lójijì ni wọn kọ lu awọn eeyan awọn, tawọn marun-un ti fara pa loju ẹsẹ. Bẹẹ ni wọn tun dana sun ọkan lara awọn ọkọ tawọn fi n polongo ibo, tí wọn si tun ba awọn mi-in jẹ kọja atunṣe.

Fasua ni ohun to ya awọn lẹnu ju ni bi awọn ọlọpaa to wa nibi iṣẹlẹ naa ṣe n woran, tí wọn ko si ri ohunkohun ṣe nipa akọlu naa titi ti wọn fi ṣe ifẹ inu wọn tan.

Awọn eeyan kan lo ni wọn fẹyin pọn Jẹgẹdẹ wọ aafin Ọlọba tilu Ọba lọ ti wọn ko fi rí i ṣe leṣe

Agbẹnusọ Jẹgẹdẹ yii ni iru akọlu bayii ti kọkọ waye ni Ayede-Ọgbese, nijọba ibilẹ Ariwa Akurẹ, lọjọ bii marun-un sẹyin, nibi tawọn tọọgi ẹgbẹ APC ti dana sun ọkọ meji to jẹ ti PDP, ti wọn si tun ṣa pupọ ninu awọn eeyan awọn ladaa yannayanna.

O waa bẹ Aarẹ Muhammed Buhari lati tete wa nnkan ṣe sọrọ naa, ko si da Akeredolu lẹkun akọlu tawọn ọmọlẹyin rẹ n ṣe sawọn ni gbogbo igba kọrọ naa too di ohun ti apa ko ni i ka mọ.

Gbogbo akitiyan wa lati ba Alukoro ẹgbẹ APC ipinlẹ Ondo, Alex Kalẹjaye sọrọ lo ja si pabo.

 

Leave a Reply