Monisọla Saka
O kere tan, eeyan mẹrin ninu awọn alatilẹyin Peter Obi ti i ṣe oludije dupo aarẹ lẹgbẹ oṣelu Labour Party, lawọn ẹni ibi kan kọ lu, lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kọkanla, oṣu Keji, ọdun yii, lasiko ti wọn lọ sinu papa iṣere nla TBS, nipinlẹ Eko, fun eto ipolongo ẹgbẹ wọn.
Gẹgẹ bi alaye tawọn tọrọ ṣoju wọn ṣe ati fọnran fidio to ja ran-in lori ẹrọ ayelujara, ada atawọn nnkan ija mi-in ni wọn ko ti awọn eeyan yii, lasiko ti wọn n lọ sibi ipolongo wọn. Lẹyin ti wọn ṣe wọn leṣe tan ni wọn tun ba ọpọlọpọ mọto ti wọn ba ti ri ami idanimọ ẹgbẹ Labour Party lara ẹ kọja bo ṣe yẹ.
Agbẹnusọ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Benjamin Hundenyin, to fidi iṣẹlẹ yii mulẹ lori ẹrọ abẹyẹfo Twitter rẹ sọ pe, alaga ẹgbẹ naa ni wọọdu Jakande lo fọrọ yii to awọn ọlọpaa teṣan Ilasan leti.
O ni, “Eeyan mẹrin ti wọn fara pa ọhun ti n ri itọju, wọn si ti n ṣe gbogbo itọju to yẹ fun wọn ki ara wọn le tete pada bọ sipo.
Ọga ọlọpaa teṣan Ilasan ti bẹrẹ iwadii, ṣugbọn ẹka ileeṣẹ ọlọpaa to n ri si iwadii iwa ọdaran nipinlẹ yii, SCID, yoo tẹsẹ bọnu iwadii naa laipẹ.
“Ni nnkan bi ibusọ mẹẹẹdogun sibi ti wọn ti fẹẹ ṣeto ipolongo ibo ọhun ni wọn ti kọ lu wọn. Gẹgẹ ba a ṣe ti sọ tẹlẹ, awọn ẹka SCID yoo dide lati gba iwadii naa lọwọ agọ ọlọpaa Ilasan, lati le ri awọn ti aje iwa ibajẹ naa ṣi mọ lori mu kiakia.
Awọn eeyan ti wọn fara pa ọhun atawọn ẹlẹrii mi-in ti wa nikalẹ lati ran awọn agbofinro lọwọ, lori awọn nnkan ti wọn le nilo lati le tete ri awọn eeyan buruku ọhun mu”.
Nigba to n bu ẹnu atẹ lu iwa ika ati ọdaju tawọn ẹni ọhun hu, Hundenyin ni lati ọjọ Ẹti, Furaidee, ni wọn ti fọn awọn ẹṣọ alaabo kaakiri ibudo ipolongo ibo ọhun, lati le dena ọwọkọwọ tawọn arufin le fẹẹ gbe lati da omi alaafia ibẹ ru, pẹlu bi wọn si ṣe palẹmọ to naa, wọn tun pada ṣiṣẹ ọwọ wọn naa ni”.
Pẹlu bo ṣe jẹ ipinlẹ ta a le pe ni ti ẹgbẹ oṣelu APC, to si tun jẹ pe ọmọ ẹgbẹ APC lo wa lori aleefa, bii omi lawọn eeyan tu jade lọjọ Abamẹta yii lati fi atilẹyin wọn han fun Obi.
Ọpọlọpọ awọn alatilẹyin ẹ yii ni wọn ti de inu TBS, ti wọn ti n reti rẹ pe ko de, nigba tawọn mi-in si kora wọn jọ pọ si ilu Ikẹja, nipinlẹ Eko. Awọn ti wọn n bọ loju ọna lawọn janduku yii lọọ dena de, ti wọn fi ṣe wọn leṣe, ti wọn si tun ba mọto atawọn nnkan ini wọn jẹ.
Peter Obi bara jẹ lori iṣẹlẹ naa, o ṣapejuwe ẹ gẹgẹ buii eyi to ba ni lọkan jẹ jọjọ, o waa ke si awọn ọlọpaa pe ki wọn tete ba awọn wa awọn ọbayejẹ naa jade.
Ko too di pe o de si TBS, Obi ti kọkọ lọọ ba awọn oniṣowo ninu ọja Alaba International Market, agbegbe Ọjọ, nipinlẹ naa lalejo, tẹrin-tọyaya ni wọn si fi ki i kaabọ. Bi wọn ṣe n juwọ si i, ti wọn n mi asia ẹgbẹ wọn loke, bẹẹ ni gbogbo wọn n pariwo orukọ ẹ pẹlu ayọ ati idunnu gidi.
Bo tilẹ jẹ pe ko sẹni to ti i mọ awọn ti wọn ṣiṣẹ ibi yii ati idi ti wọn fi ṣe e, awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Labour Party yii ni ọkan lara olori awọn ẹgbẹ oṣelu to fẹsẹ rinlẹ nipinlẹ naa lo wa nidii ikọlu ọhun.