Florence Babaṣọla, Oṣogbo
O kere tan, eeyan marun-un lo fara pa, ti ọkọ ayọkẹlẹ meji si bajẹ, lasiko ti awọn tọọgi kọ lu si kọmiṣanna fun ọrọ iṣẹ-ode ati irinkerindo ọkọ tẹlẹ nipinlẹ Ọṣun, Ọnarebu Rẹmi Ọmọwaiye.
Aago mẹfa irọlẹ kọja iṣẹju diẹ lọjọ Ẹti, Furaidee, ọsẹ yii, la gbọ pe iṣẹlẹ naa ṣẹlẹ ninu ọja Iṣida, nijọba ibilẹ Iwọ-Oorun Ileṣa, nipinlẹ Ọṣun.
Ounjẹ ọdun Keresimesi bii maaluu ati irẹsi la gbọ pe Ọmọwaiye atawọn adari ẹgbẹ oṣelu APC lagbegbe naa gbe lọ sọdọ awọn eeyan ibẹ ti awọn tọọgi ọhun fi ya bo wọn.
Lara awọn ti wọn fara kaasa wahala naa ni olori awọn ọdọ ẹgbẹ APC ni Wọọdu 3, Ọpẹyẹmi Ọkẹ, Tosin Adanlawọ, Ọgbẹni Ọdẹkunle, Ọgbẹni Ojo Agboọla, ati Ọgbẹni Junior Ọlaọjaoke ti wọn jẹ ọmọ ẹgbẹ oṣelu naa, gbogbo wọn si n gba itọju lọwọ nileewosan kan bayii.
A gbọ pe bi eto ṣe bẹrẹ lawọn tọọgi naa ṣigun de, ti wọn si bẹrẹ si i yinbọn lakọlakọ si mọto to gbe Ọmọwaiye lọ sibẹ atawọn to tẹle e.
Nigba to n ba Alaroye sọrọ, Ọmọwaiye ṣalaye pe awọn ti oun da mọ lawọn ti wọn ṣaaju wahala naa, ọmọ ẹgbẹ oṣelu PDP n’Ileṣa si ni wọn.
O ni oun gan-an ni wọn ni lọkan ti wọn fi wa, nitori gbogbo ara Toyota Highlander ti oun gbe lọ sibẹ lo kun fun ọta ibọn.
O sọ siwaju pe awọn ti lọọ fi iṣẹlẹ naa to awọn agbofinro ti wọn wa ni Ayesọ leti fun iwadii to peye lori ẹ.
Ṣugbọn nigba to n sọrọ lori iṣẹlẹ naa, alakooso eto iroyin fun ẹgbẹ PDP l’Ọṣun, Ọladele Ọlabamiji, ṣalaye pe iwa Ọmọwaiye lo n tọ ọ lẹyin.
Ọladele ni ere iṣẹ ọwọ kọmiṣanna ana ọhun lo n jẹ nitori awọn to ti figba kan gbogun ti niluu Ileṣa ni wọn n gbẹsan, ọrọ naa ki i ṣe ti ẹgbẹ oṣelu rara.
O waa ke si awọn ọlọpaa lati ṣewadii Ọmọwaiye funra rẹ, lati le fidi otitọ mulẹ lori ọrọ naa.