Oluyinka Soyemi, Ado-Ekiti
Wahala nla lo ṣẹlẹ lọṣan-an ọjọ Iṣẹgun, Tusidee, niluu Ado-Ekiti, ti i ṣe olu-ilu ipinlẹ Ekiti, pẹlu bi awọn tọọgi ṣe kọ lu awọn to n ṣewọde ta ko SARS niluu naa.
Awọn tọọgi ọhun tawọn eeyan fura si gẹgẹ bii ọmọ ẹgbẹ onimọto lo ko ada, igi atawọn nnkan ija oloro mi-in, ti wọn si kọ lu awọn oluwọde lagbegbe Adebayọ.
Awọn afurasi ọhun la gbọ pe wọn n binu si bi idaduro ṣe ba eto ọrọ-aje ipinlẹ naa.
Niṣe lawọn oluwọde to laya koju awọn tọọgi ọhun, tawọn ti ko le duro si sa asala fẹmi-in wọn, eyi si fa ipalara fun ọpọlọpọ eeyan, eyi to fi mọ awọn to kan n kọja lọ.
Nigba ta a pe Alukoro ọlọpaa Ekiti, Sunday Abutu, o ni wọn ko ti i sọ iṣẹlẹ naa foun.
Ẹwẹ, ijọba ipinlẹ Ekiti ti kede pe gbogbo ileewe ti di titi pa lati asiko yii lọ titi di ipari ọse yii.
Kọmiṣanna feto ẹkọ, imọ sayẹnsi ati imọ ẹrọ, Ọmọwe Ọlabimpe Aderiye, lo kede ọrọ naa. O ni igbesẹ naa waye lati daabo bo ẹmi awọn olukọ ati akẹkọọ, gbogbo wọn yoo si wọle lọjọ Aje, Mọnde to n bọ.