Ibrahim Alagunmu, Ilọrin
Awọn ẹgbẹ oṣiṣẹ ilẹ wa, Labour Congress (NLC ati TUC), ẹka ti ipinlẹ Kwara, ti wọn darapọ mọ awọn ẹgbẹ wọn jake-jado orilẹ-ede Naijiria, lati ṣayẹyẹ ayajọ ọjọ awọn oṣiṣẹ l’Ọjọruu, Wẹsidee, ọjọ kin-in-ni, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii.
Lasiko ti alaga ẹgbẹ yii ni Kwara, Muritala Saheed Ọlayinka, n ba awọn ọmọ ẹgbẹ yooku ṣọrọ ni papa Iṣere ipinlẹ Kwara (Kwara State Stadium), lo ti ki gbogbo awọn oṣiṣẹ ipinlẹ naa ku afarada bi ilu ṣe ri lasiko yii, bakan naa lo dupẹ lọwọ Gomina Abdulrasaq, fun ipa to ti ko ninu aye awọn oṣiṣẹ.
Lẹyin eyi lo sọ pe nnkan mọkanlelogun (21), ni oniruuru ipenija tawọn oṣiṣẹ ipinlẹ Kwara n koju, tawọn si n beere fun idahun kiakia lati ọwọ gomina. Lara awọn ibeere ọhun ni pe awọn fẹ ki gomina lo ipo rẹ gẹgẹ bii alaga awọn gomina lati fi apẹẹrẹ rere lelẹ fun awọn gomina yooku nipa ṣiṣe afikun owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju lọ ni kete ti ijọba apapọ ba ti bẹrẹ si i san an fawọn oṣiṣẹ ijọba apapọ.
Bakan naa ni wọn tun fitara sọrọ pe awọn fẹ kijọba fun awọn ijọba ibilẹ ni ominira. Alaga ẹgbẹ NLC, ni lara iṣoro tawọn n koju ni pe ijọba ki i gba oṣiṣẹ miiran rọpo awọn to n fẹyinti lẹnu iṣẹ, leyii to mu ki iṣẹ pọ ju awọn oṣiṣẹ lọ.
Wọn rọ ijọba Kwara, ko tete gbe awọn igbimọ dide lati wa ọna abayọ si ọrọ owo-oṣu oṣiṣẹ to kere ju lọ, nitori pe lori ọrọ owo-oṣu oṣiṣẹ tuntun ọhun, wọn ko ti i jokoo, depo pe wọn yoo ṣe nnkan kan.
O tun ni awọn fẹ ki gomina ṣe atunṣe si ilee-igbepo (NNPC DEPOT), to wa ni Òkè-Òyì, nipinlẹ naa, nitori pe ipo to wa bayii n ṣe akoba fun eto ọrọ-aje ipinlẹ naa.