Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ṣe ni ariwo, “Obidient” gba gbogbo ilu nla nla nipinlẹ Ọṣun laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ti i ṣe ọjọ ayajọ ọdun kejilelọgọta ti Naijiria gba ominira labẹ awọn oyinbo Biritiko.
Awọn ọmọ ẹgbẹ oṣelu Labour ni wọn fọn sita pẹlu asia ẹgbẹ wọn lọwọ, wọn wọ aṣọ ti wọn ya aworan oludije funpo aarẹ wọn, Peter Obi, si lara.
Kaakiri ijọba ibilẹ mẹrẹẹrin to wa niluu Ileefẹ; Guusu Ifẹ, Ila-Oorun Ifẹ, Aarin Gbungbun Ifẹ ati Ariwa Ifẹ, ni awọn ọmọ ẹgbẹ naa ti jade sita, ti wọn si bẹrẹ iwọde wọọrọwọ alayọ naa ni Afẹwọnrọ Park, Enuwa niluu Ileefẹ.
Eredi irin naa, eleyii ti wọn rin kaakirin ilu Ileefẹ, gẹgẹ bi Alakooso wọn, Ọlamide Awosunle, ṣe sọ ni lati la awọn araalu lọyẹ nipa iru aarẹ to yẹ ki wọn dibo fun loṣu Keji, ọdun 2023.
O ni idi ti awọn fi jade sita lati ba awọn araalu sọ nipa gomina ipinlẹ Anambra tẹlẹ ọhun ni lati jẹ ki wọn mọ pe orileede yii nilo irufẹ awọn aṣaaju tuntun.
O ni, “A ko le tẹ siwaju labẹ awọn adari ti wọn ti sọ Naijiria di ogun-ini ara wọn. Awọn ti wọn gba pe ko si ara ti awọn ko le fi Naijiria da, ti wọn si n ṣe wa bo ṣe wu wọn.
“Afojusun wa ni lati paroko ranṣẹ si awọn aṣaaju wa pe wọn ti su wa, ki a si jẹ ki awọn eeyan wa mọ pe a ti ni ẹgbẹ oṣelu to le gba wa ninu ọfin ti wọn ti ju wa si bayii.
“Ohun ti a fẹẹ sọ fun gbogbo ọmọ Naijiria ni pe a gbọdọ ṣiṣẹ papọ fun orileede tuntun ti a fẹ, a ko gbọdọ gba owo lọwọ awọn adari ti a fẹẹ le danu. Ṣugbọn ti ẹnikẹni ba fẹẹ gba owo lọwọ wọn, owo wa ti wọn ti ji ko naa ni, ẹ gba a, ki ẹ si dibo yin fun Peter Obi gẹgẹ bii aarẹ wa”.
Bakan naa niluu Oṣogbo, tilu-tifọn lawọn ọmọ ẹgbẹ naa jade, bi wọn ṣe n kọrin ni wọn n jo, ti wọn si n fi iwe pelebe-pelebe le awọn araalu lọwọ lati le jẹ ki wọn mọ pe ‘Obidient’ lawọn.
Ọkan lara wọn, Tẹjumade Ọlagunju, ṣalaye fawọn oniroyin pe lẹyin ti awọn ti ṣayẹwo gbogbo awọn ti wọn jade funpo aarẹ finnifinni, ti awọn si ri i pe Peter Obi lo gbewọn ju laarin wọn, lawọn pinnu lati ṣatilẹyin fun un ati lati sọ fun awọn araalu nipa rẹ.