Aye le o! Lẹyin ti ọga Zainab fipa ba a lo pọ tan lo ni ki wọn lọọ pa a 

Gbenga Amos, Ogun

Ọga telọ, to lawọn ọmọ ẹkọṣẹ lọkunrin lobinrin lọdọ ni Sulaimon Oriọla, niluu Owode-Ẹgba, nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipinlẹ Ogun, ṣugbọn ọkunrin naa ti dero ahamọ awọn ọlọpaa bayii, ọkan lara awọn ọmọọṣẹ ẹ, Zainab, ọmọọdun mẹrindinlogun pere, lo ki mọlẹ, to si fipa ba a laṣepọ. Igba tawo ọrọ naa si fẹẹ ya, wọn lo ran awọn agbanipa sọmọbinrin ọhun, bi ko ba si si ti Ọlọrun to yọ ọmọ ọhun ni, diẹ lo ku ki wọn da ẹmi ẹ legbodo.

ALAROYE ṣabẹwo si ilu Owode-Ẹgba, nibi ti awọn aladuugbo ti ṣalaye ohun to ṣẹlẹ fun wa. Obinrin to wa nitosi ile awọn ọmọbinrin naa ti ko fẹ ka darukọ oun ṣalaye pe  laarin ọsẹ to lọ lọhun-un niṣẹlẹ yii waye.

Wọn ni ṣọọbu ti Sulaimọn ti n ṣiṣẹ aranṣọ, to wa lọna Peaceful, niluu Owode-Ẹgba, lọmọbinrin yii atawọn ẹlẹgbẹ rẹ yooku ti n kọṣẹ faṣọn disaina (fashion designer), ṣugbọn irọlẹ ni Zainab maa n fabọ si ṣọọbu ọhun lẹyin to ba dari de lati ileewe to n lọ.

‘Lọjọ kan, ọmọbinrin yii n bọ lati ileewe rẹ, lo ba pade ọkan ninu awọn bọisi adugbo, iyẹn ba da a duro lọna, o n ba a sọrọ. Ẹnikan to ri awọn mejeeji lo lọọ ṣofofo fun ọga rẹ pe oun ri Zainab pẹlu awọn gende kan ti wọn jọ n sọrọ.

Nigba tọmọ naa de ṣọọbu, ọga rẹ beere ẹni to n ba sọrọ lọna, o si bẹrẹ si i bu u pe onirinkurin ni, lo ba ni ko kọja si ile oun, iyẹn ile ọga rẹ to wa lẹyin ṣọọbu ọhun, o loun maa lọọ da sẹria fun un nibẹ. Nigba ti ọga pada lọọ ba a ninu ile naa, wọn lo paṣẹ fun ọmọọsẹ yii pe ko bọ ẹwu ẹ, ko bọ buresia ẹ, lo ba ku pata nikan nidii ọmọ ọhun. Lẹyin eyi lo ni ko kunlẹ, ko kawọ ẹ soke, ko si diju.

Wọn niyawo Sulaimọn naa wa nibẹ ti gbogbo eyi fi n ṣẹlẹ, ṣugbọn ọkunrin naa pada ran iyawo ẹ niṣẹ, o ni ko lọọ ba oun ra nnkan kan wa. Gẹrẹ tiyawo rẹ jade lo bọ pata nidii ọmọọṣẹ rẹ yii, o si ba a laṣepọ tipatipa.

A gbọ pe ọmọbinrin yii rojọ iṣẹlẹ ọhun fun ọkan ninu awọn ti wọn jọ n kọṣẹ telọ ti wọn n pe ni Pẹlumi. Pẹlumi yii lo ko ọga rẹ loju, o sọ ohun to gbọ fun un, ṣugbọn ọga naa ni irọ ni Zainab pa m’ọun, iru iṣẹlẹ bẹẹ ko waye.

Lẹyin naa ni wọn ni afurasi ọdaran yii lọọ ba mama ọmọdebinrin naa sọrọ, wọn lo tun lọọ ba pasitọ ṣọọṣi kan pe ki wọn ba oun ṣe e ti mama ọmọ naa ko fi ni i mọ nnkan to ṣẹlẹ, o loun o fẹ ki akara tu sepo.  Bẹẹ lo tun lọọ ba aafaa kan pe ki wọn ba oun ṣe e tiyaa ọmọ naa ko fi i ni i ranti ohun to ṣẹlẹ tabi ba oun ja lori ẹ. Ṣugbọn nigba to ri i pe ọrọ naa ti bẹrẹ si i ja ranyin laduugbo, o bẹsẹ rẹ sọrọ, o sa lọ.

Wọn lawọn ọlọpaa kọkọ mu pasitọ ati aafaa naa nigba tọrọ yii de teṣan, ṣugbọn nigba to ya, wọn tu awọn mejeeji silẹ, tori wọn o mọwọ mẹsẹ.

Ọjọ mẹrin lẹyin naa, wọn lafurasi ọdaran yii lọọ rẹbuu ọmọbinrin yii lọna nigba tiyẹn n bọ lati ṣọọṣi to lọ, o si da a duro. Bibojuwẹyin tọmọbinrin naa wẹyin, niṣe lawọn gende meji kan yọ si i, ni wọn ba faṣọ dudu bo o loju, wọn tun di i lẹnu, ni wọn ba wọ ọ lọ sinu agbo ọgẹdẹ kan ninu igbo.

Ọmọbinrin naa loun gbọ tawọn agbanipa naa n sọ pe ‘Zainab, pipa la fẹẹ pa ẹ yii o, oku ẹ o gbọdọ da wa laamu o, Sulaimon ni ki oku ẹ maa lọọ ba ja o,’ ati bẹẹ bẹẹ lọ. Lẹyin naa ni wọn ju ọmọbinrin naa sinu koto kan, wọn si ba tiwọn lọ.

Wọn lori lo ko ọmọbinrin yii yọ, o rapala kuro ninu koto naa, niṣe lo si fori jagbo titi to fi dọgbọn de aarin ilu pada, gbogbo ara rẹ lo bẹjẹ, ẹgun ti ya a lara yannayanna.

Nigba ti wọn mu ọmọbinrin yii de ọdọ ọga rẹ, wọn ni niṣe lẹnu ya a, boya nitori ko lero pe ọmọ naa ṣi maa wa laaye ni. Eyi lo jẹ kawọn agbofinro mu un, to si dero ahamọ.

ALAROYE ba iya ọmọbinrin yii sọrọ, o si kọkọ gba lati ṣalaye bọrọ naa ṣe jẹ fun wa, ṣugbọn nigba ti akọroyin wa n lọọ ba a nibi to ti ni ka pade lo tun loun ko si nile.

Bakan naa la pe Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ogun, SP Abimbọla Oyeyẹmi, a si tun fi atẹjiṣẹ ṣọwọ soju opo Wasaapu rẹ, ṣugbọn ko ti i fesi titi ta a fi pari akojọpọ iroyin yii.

Leave a Reply