Aye ti bajẹ o, ohun ti baba yii ṣe fun ọmọ bibi inu ẹ l’Akurẹ, buru jai

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Aṣa ki baba maa ki ọmọ to bi ninu ara rẹ mọlẹ, ko si maa ba a lo pọ n fẹ amojuto ijọba atawọn tọrọ kan pẹlu bo ṣe di pe kinni naa n fojoojumọ buru si, ti ki i ṣi i ṣe aṣa tabi iwa to bojumu lawujọ wa. Koda, ofin Naijiria paapaa ko faaye gba a. Baba ẹni ogoji ọdun kan, Achibong Abraham, lọwọ ti tun tẹ bayii lori ẹsun pe lati bii ọdun mẹfa sẹyin lo ti n fipa ba ọmọ bibi inu rẹ sun.

ALAROYE fidi eleyii mulẹ ninu atẹjade kan ti Alukoro ajọ sifu difẹnsi nipinlẹ Ondo, Ọgbẹni Daniel Aidamenbor, fi ṣọwọ si akọroyin wa. O ni latigba ti ọmọdebinrin to forukọ bo laṣiiri ọhun ti wa lọmọ ọdun mẹjọ pere ni baba rẹ ti n fipa ba a lo pọ.

Aidamenbor ni, Achibong ko jawọ ninu iwa buruku naa titi aṣiri rẹ fi pada tu lẹyin ti ọmọdebinrin ọhun pe ọmọ ọdun mẹrinla geere laipẹ yii.

O ni awọn eleto ilera ijọba kan ni wọn lọ sileewe ti ọmọbìnrin naa ti n kẹkọọ laipẹ yii lati lọọ la awọn olukọ atawọn akẹkọọ lọyẹ lori pataki lilo oogun lati dena ajakalẹ arun.

A gbọ pe bi awọn oṣiṣẹ eleto ilera naa ṣe pari ohun ti wọn waa ṣe ti wọn si ba tiwọn lọ ni ọmọ ọdun mẹrinla yii mu ara rẹ lọkan le, to si lọọ funra rẹ ṣalaye awọn nnkan to ti n foju wina lati ọwọ baba to bi i lọmọ lati bii ọdun mẹfa sẹyin.

Kiakia lawọn olukọ to lọọ fọrọ lọ mori le ọfiisi ajọ sifu difẹnsi lati fi iroyin kayeefi ti eti wọn ṣẹṣẹ gbọ tan to wọn leti.

Aidamenbor ni lọgan lawọn ti fi pampẹ ofin gbe ọkunrin naa lọ si ọfiisi awọn, nibi to ti fẹnu ara rẹ jẹwọ pe loootọ loun n ba ọmọ toun bi ninu oun sun.

O ni awọn ti n ṣeto bi ọkunrin naa yoo ṣe foju bale-ẹjọ ni kete ti iwadii ba pari patapata lori ẹsun ti wọn fi kan an.

 

Leave a Reply