Aye ti bajẹ o, ọmọ ọdun meji ni Nathaniel fipa ṣe ‘kinni’ fun

Adewale Adeoye

Awọn alaṣẹ ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Egba, nijọba ibilẹ Uhunmwande, nipinlẹ Edo, ti sọ pe ọdọ awọn ni ọdọmọdekunrin kan, Nathaniel Ogenochukwu, ẹni ọdun mẹrindinlogun kan wa, tawọn si n ṣewadii nipa ẹsun ti wọn fi kan an. Wọn ni gbara tawọn ba ti pari iwadii awọn tan lawọn maa foju rẹ bale-ẹjọ.

ALAROYE gbọ pe ẹsun ti wọn fi kan Nathaniel ni pe o fipa ba ọmọọdun meji kan sun nile awọn obi rẹ laipẹ yii. Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ naa, S.P Chidi Nwabuzor, to ṣafihan Nathaniel fawọn oniroyin lakooko ti wọn n sọ aṣeyọri awọn ọlọpaa lati gbogun ti iwa ọdaran laarin ilu naa sọ pe awọn ajọ kan to n gbogun ti ifipa ba ni lo pọ laarin ilu lo lọọ fọrọ Nathaniel to awọn ọlọpaa leti, tawọn si tara ṣaṣa lọọ fọwọ ofin mu un nile awọn obi rẹ.

Ṣa o, Nathaniel paapaa  ti jẹwọ pe oun ko mọ ohun to kọ lu oun rara toun fi hu iwa radarada naa pẹlu ọmọọdun meji naa.

Nathaniel ni, ‘Afi bii eedi lọrọ ọhun jọ o, ki i ṣe igba akọkọ ree ti ọmọ naa maa wa sile wa, ẹgbọn mi kan ni ọmọ naa maa n waa ba ṣere. Lọjọ ti eṣu ya mi lo yii, gbara ti ọmọ naa dele wa ni mo ti sọ fun un pe ẹgbọn mi to maa n waa ba ṣere ko si nile, ṣugbọn ọmọ naa kọ, ko pada lọ sile wọn. Ṣe lo taku pe oun ko ni i lọ. Bi mo ti ṣe tan an wọle niyẹn o, ti mo si bọ nika kekere kan bayii to wọ sidii, kẹ ẹ si maa wo o, mi o ki ‘kinni’ mi bọ ọ loju ara tan o, o daju pe aarin itan ọmọ naa ni mo ki ‘kinni’ mi bọ, ki i ṣe oju ara rẹ gan-an, igba akọkọ mi ree ti ma a dan iru nnkan bẹẹ wo, o si da mi loju pe iṣẹ ọwọ eṣu ni ohun ti mo ṣe yii.

Nwabuzor ti sọ pe gbara tawọn ba ti pari iwadii awọn lawọn maa foju Nathaniel bale-ẹjọ.

Leave a Reply