Adewale Adeoye
Ọwọ ileeṣẹ ọlọpaa agbegbe Zone 2, Onikan, nipinlẹ Eko, ti tẹ ayederu kọsitọọmu kan, Abilekọ Rakiya Musa, ẹni ti wọn fẹsun kan pe ṣe lo n lu awọn araalu ni jibiti owo nla pẹlu bo ṣe maa n parọ fun wọn pe oun maa ba wọn ra lara mọto ti ileeṣẹ kọsitọọmu fẹẹ lu ni gbanjo lowo pọọku.
ALAROYE gbọ pe o ti pẹ ti Musa ti n lu awọn eeyan ni jibiti owo nla, ko too di pe ọwọ ṣẹṣẹ tẹ ẹ laipẹ yii.
Alukoro ẹka ileeṣẹ ọlọpaa Zone 2, nipinlẹ Eko, ZPRO, S.P Hauwa Idris-Adamu, lo fidii ọrọ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹwaa, oṣu Kẹfa, ọdun yii.
O ṣalaye pe awọn meji kan, Ọgbẹni Josiah Kashin Utenwojo, ati Ọgbẹni Dominic Okoh Henry, ti Musa lu ni jibiti miliọnu mẹta o le ẹgbẹrun lọna igba Naira (N3.2M), ni wọn kọ lẹta ifẹhonu han si ọga ọlọpaa AIG to n mojuto iṣakooso Zone 2 ọhun, ti wọn si sọ bi Musa ti wọn lo n gbe ninu baraaki ologun oju ofurufu tẹlẹ, ti ṣe lu wọn ni jibiti owo nla naa.
Alukoro ni, ‘Oju-ẹsẹ ti ọga ọlọpaa ti gba lẹta awọn eeyan ti wọn fejọ Musa sun lo ti yan akanṣe ikọ ọlọpaa kan pe ki wọn bẹrẹ iṣẹ nipa ẹsun ti wọn fi kan Musa. Ohun tawọn to lu ni jibiti sọ ni pe Ajagun-fẹyinti kan, Akinwande Kayọde, to jẹ ọmọ oju ogun ofurufu ilẹ wa lo ṣe atọna bawọn ṣe pade Musa, tawọn si sanwo mọto to ṣeleri lati ba awọn ra sinu akanti UBA rẹ kan. Ṣugbọn gbara ti owo wọ akaunti obinrin yii lawọn ko ti ri i pe lori foonu rẹ mọ.
Nigba tawọn ọlọpaa ti AIG ni ki wọn ṣewadii Musa maa fi ri i mu, ilu Abuja, nibi to sa lọ, lọwọ ti tẹ ẹ, ti wọn si fọwọ ofin mu un wa siluu Eko.
Obinrin ayederu kọsitọọmu yii ti jẹwọ pe loootọ loun gbowo lọwọ awọn ti wọn fẹjọ oun sun ni Zone 2 naa. O ni o ti le lọdun mẹẹẹdogun toun ti n lu awọn eeyan ni jibiti, ko too di pe ọwọ ṣẹṣẹ tẹ oun laipẹ yii.
Siwaju si i, Musa ni gbara toun ti gbowo naa lọwọ awọn toun lu ni jibiti loun ti fun Akinwande to jẹ ọrẹkunrin oun ni miliọnu kan Naira ninu ẹ.
Lara awọn ẹru ofin ti wọn ba lọwọ rẹ ni ayederu kaadi idanimọ kọsitọọmu kan atawọn ohun miiran to fi han gbangba pe ọjọ pẹ ti Musa ti n lu awọn araalu ni jibiti.
Wọn ti sọ pe ti awọn ba ti pari iwadii nipa ẹsun jibiti ti wọn fi kan Musa, lawọn yoo foju rẹ bale-ẹjọ.