Monisọla Saka
Nitori awọn aṣiri aṣemaṣe ti awọn eeyan n ṣe pẹlu bi ọkọ sẹ n lajọṣepọ pẹlu ẹlomi-in nita, ti iyawo naa si n tẹ ara silẹ fun awọn ọkunrin mi-in yatọ si ọkọ to fẹ ẹ silẹ to n fojoojumọ tu sita bayii, gbajumọ ọkunrin to maa n gbe awọn olorin jade to jẹ alaṣẹ ati oludasilẹ ileeṣẹ ti wọn n pe ni Mavin records, Michael Collins Ajereh, tawọn eeyan mọ si Don Jazzy, ti ke sawọn ọkunrin ẹgbẹ ẹ lati mu ayẹwo ẹjẹ ti yoo fi baba ọmọ han, iyẹn DNA, ni ọkunkundun, ki ọkan wọn le balẹ pe awọn lawọn lọmọ.
Don Jazzy ni ayẹwo ẹjẹ (DNA) daa, bẹẹ lo tun ṣe pataki ju ki wọn da inawo ikomọ rẹpẹtẹ kalẹ lọ, nitori ọna lati fidi ẹni to ni ọmọ mulẹ ni ayẹwo naa wa fun.
Ọkunrin to fi ọgọrun-un miliọnu Naira ṣe atilẹyin fun ileeṣẹ ti ki i ṣe ti ijọba (NGO), ti ajijagbara ori ayelujara nni, Martins Otse, ti wọn n pe ni VDM, da silẹ faraalu laipẹ yii kọ ọ pe, “DNA ṣe pataki ju inawo ikomọ lọ”.
Ọrọ yii ti di ohun tawọn eeyan n gba bii ẹni gba igba ọti, paapaa, lori ayelujara.
Bo tilẹ jẹ pe ọkunrin yii ko doju ọrọ kọ eeyan kan ni pato, o ṣee ṣe ko jẹ wahala ayẹwo ẹjẹ ati ọrọ ọmọ ale to pọ nita lasiko yii lo mu ko sọ bẹẹ.
Bẹẹ tun ni ọrọ ọkunrin minisita kan lorilẹ-ede Equatorial Guinea, Baltasar Engonga, ti fidio ibi to ti ba awọn obinrin bii irinwo lajọṣepọ lasiko ọtọọtọ, titi kan iyawo ẹgbọn ẹ ati obinrin alaboyun gba lori ayelujara, le mu ki Don Jazzy ro pe ṣiṣe ayẹwo ẹjẹ ni kete ti ọmọ ba ti daye le dẹkun ipaya, ibanujẹ ati ọpọ idile to n dun tiru ọrọ bẹẹ le tuka lọ.