Ọmọ ẹgbẹ okunkun yinbọn lu awọn ọlọpaa to da a duro

Faith Adebọla

Baale ile ẹni ọdun mẹtalelọgbọn (33) kan, Idris Ayinla, ti ha sakolo awọn ọlọpaa ọtẹlẹmuyẹ bayii, o si ti n jẹwọ ibi to ti ri ibọn oloju meji ti wọn ka mọ ọn lọwọ, ati ohun to ro to fi pinnu lati darapọ mọ ẹgbẹ okunkun, ati idi to fi yinbọn mọ awọn ọlọpaa ti wọn da a duro nirona.

Ninu atẹjade kan ti Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Eko, SP Benjamin Hundeyin, fi ṣọwọ s’ALAROYE lori ikanni Wasaapu rẹ lo ti ṣalaye pe awọn ọlọpaa ikọ ayara-bii-aṣa, Rapid Response Squad (RRS), Eko, ni wọn pade ọkọ ayọkẹlẹ Toyota Matix ti afurasi ọdaran yii ati awọn ẹlẹgbẹ rẹ kan ko ara wọn kun inu ẹ bamu laaarọ ọjọ Abamẹta, Satide, ọjọ kẹjọ, oṣu Keje, ọdun 2023 yii.

Ọkọ ayọkẹlẹ ti wọn kun lọda pupa foo, ti wọn pe nọmba rẹ ni EKY 638 EX naa dori kọ agbegbe Oniru, ni Lẹkki, l’Erekuṣu Eko. N lawọn ọlọpaa RRS ti wọn n ṣe patiroolu ni Admiralty Way, n’Ikoyi, ba da a duro. Bi dẹrẹba ọkọ naa ṣe duro tawọn ọlọpaa fẹẹ beere iwe ọkọ rẹ, niṣe lọkan ninu awọn bọisi to wa ninu ọkọ ọhun na owo abẹtẹlẹ si wọn pe ki wọn gba, ki wọn jẹ k’oun maa ba t’oun lọ, o lawọn n lọ si etikun lọọ ṣe faaji ni. Awọn ọlọpaa yii ko gba owo naa, wọn ṣaa fi dandan le e pe awọn maa yẹ ọkọ ayọkẹlẹ naa wo ni.

O jọ pe awọn afurasi naa woye pe afaimọ ki akara ma tu sepo nibi tawọn wa yii. Bi wọn ṣe n ṣilẹkun ọkọ lati bọọlẹ bii pe wọn fẹẹ waa da awọn ọlọpaa lohun, niṣe ni kaluku wọn ki ere mọlẹ lojiji, ti wọn si juba ehoro gba inu igbo lọ.

Kia lawọn ọlọpaa naa ti ran ibọn ọwọ wọn niṣẹ, ẹsẹ nibọn ti ba Ayinla Idris, lo ba ṣubu, awọn ọlọpaa si tete mu un, bo tilẹ jẹ pe awọn yooku rẹ ti sa lọ.

Ibọn atamatase kan ti wọn n pe ni semi-automatic, ati ọta ibọn rẹpẹtẹ ni wọn ka mọ ọn lọwọ, wọn si tete gbe e lọ sọsibitu, nibi ti wọn ti ba a tọju ọgbẹ ẹsẹ rẹ, lẹyin eyi lo dero ahamọ awọn ọlọpaa, nibi to wa di ba a ṣe n sọ yii.

Hundeyin ni afurasi naa ti n ran awọn ọlọpaa lọwọ lojuna ati fi pampẹ ofin gbe awọn yooku rẹ ti wọn sa lọ ọhun, tori gbogbo wọn lawọn maa mu, tawọn yoo si wọ wọn de kootu ti iwadii ba ti pari.

CP Idowu Owohunwa ti gboṣuba fawọn ọmọọṣẹ rẹ ọhun, o si rọ awọn araalu lati maa tete fi ọrọ awọn ajeji ti wọn ba kẹẹfin, tabi awọn ti wọn ba wa oniṣegun to maa ba wọn tọju ọgbẹ ibọn, to ileeṣẹ ọlọpaa leti fun igbesi to yẹ.

Leave a Reply