Ayọ igbega ti wọn ṣẹṣẹ fun un lẹnu iṣẹ ni ọlọpaa yii n yọ to fi yinbọn paayan l‘Ekiti

Taofeek Surdiq , Ado-Ekiti

Ile-ẹjọ giga kan nipinlẹ Ekiti ti paṣẹ pe ki ọlọpaa ẹni ọdun mejidinlogoji kan, Tizhe Goji, lọọ ṣẹwọn ọdun mẹwaa nitori ẹsun ipaniyan ti wọn fi kan an.

Ọlọpaa olokun meji ọhun lo yinbọn pa Abayọmi Ọlaoye, to wa lati Eko si Ise-Ekiti fun ayẹyẹ igbeyawo kan. Nibi ti agbofinro yii ti n yọ ayọ igbega ti wọn ṣẹṣẹ fun un lẹnu iṣẹ lo ti yinbọn pa ọmọkunrin naa nileetura kan.

Iwaju Adajọ Adeniyi Familọni ni wọn gbe Goji lọ lati ṣalaye ẹnu rẹ nipa ohun to mọ nipa iṣẹlẹ ọhun.

Ẹṣun kan ṣoṣo to ni i ṣe pẹlu ipaniyan ni wọn fi kan an. Iwe ẹsun naa ka pe o yinbọn pa ọkunrin kan torukọ rẹ n jẹ Abayọmi Ọlaoye lọjọ kọkandinlọgbọn, oṣu  Keje, ọdun 2021, nileetura kan to wa ni opopona to lọ lati Ado-Ekiti si Ikẹrẹ.

Ẹsun yii ile-ẹjọ juwe gẹgẹ bii eyi to lodi, to si ni ijiya ninu iwe ofin ipinlẹ Ekiti ti wọn kọ lọdun 2012.

Bakan naa, ninu iwe kan ti wọn fi gba oun silẹ ni teṣan lakooko ti iwadii naa n lọ lọwọ, ẹlẹrii kan, Arabinrin Bukọla Ọmọrinkọba sọ pe awọn wa lati ilu Eko si ilu Isẹ-Ekiti lati waa ṣe igbeyawo ni, awọn si de si ileetura naa. O fi kun un pe ni deede aago mẹsan-an alẹ ti awọn n gbatẹgun nita ileetura yii lawọn ọlọpaa kan ṣadeede wa ọkọ wọn wọle, ti wọn bẹrẹ si i yinbọn, lasiko naa ni ibọn ba oloogbe ọhun, ti wọn si gbe e digba-digba lọ sileewosan, nibi ti awọn dokita ti kede pe o ti ku.

Lati fi idi ẹjọ rẹ mulẹ, Agbefọba ni kootu naa, Arabinrin Rachael Aladejare, pe ẹlẹrii mẹrin, bakan naa lo tun mu iwe ti wọn fi gba ohun silẹ lẹnu ọdaran naa ati iwe ayẹwo ti awọn dokita ṣe lẹyin iku oloogbe silẹ lakooko ti iwadii n lọ lọwọ gẹgẹ bii ẹsibiiti.

Nigba ti ọdaran naa n sọrọ lati ẹnu agbẹjọro rẹ, Ọgbẹni Chris Ọmọkhafẹ, o sọ pe oun lo ibọn naa lati le awọn ole kan ki oun too de ile itura naa, ṣugbọn oun gbagbe lati da a pada si ipo rẹ. O fi kun un pe ipo tuntun ati igbega ti oun ṣẹṣẹ gba ni oun waa ṣe ajọyọ rẹ nile itura naa ki iṣẹlẹ ọhun too ṣẹlẹ, lẹyin eyi lo pe ẹlẹrii kan pere.

 

Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Adeniyi Familọni, sọ pe agbefọba fi idi ipaniyan ati iṣekupani mulẹ ninu ẹjọ rẹ, o ṣalaye pe ni ilana ati ibamu bi ofin ṣe la a kalẹ, ẹwọn gbere lo yẹ ki ile-ẹjọ ran ọdaran yii, ṣugbọn kootu yoo foju aanu wo o.

Lẹyin eyi ladajọ paṣẹ pe ki ọdaran yii lọọ ṣẹwọn ọdun mẹwaa pẹlu iṣẹ aṣekara lai si owo itanran. O fi kun un pe ki ọdun mẹwaa naa bẹrẹ lati ọjọ to ti wa latimọle.

Leave a Reply