Florence Babaṣọla, Oṣogbo
Ọwọ ajọ sifu difẹnsi nipinlẹ Ọṣun ti tẹ ọmọkunrin birikila kan, Ayọbami Adedapọ, lori ẹsun ole jija.
Ayọbanmi, ẹni to n gbe l’Ojule kẹtala, lagbegbe Ọja-Ọba, niluu Oṣogbo, ni wọn fẹsun kan pe o ji tẹlifiṣan, ikoko isebẹ mẹwaa, agbada idinkara ati bẹẹ bẹẹ lọ ninu ile kan ni Ọṣunjẹla, niluu Oṣogbo.
Gẹgẹ bi Alakoso ajọ yii ṣe ṣalaye fun ALAROYE, o ni Ọjọbọ, Tọsidee, ọjọ kẹtalelogun, oṣu Karun-un, ọdun yii, lọwọ tẹ Ayọbami lẹyin to jale tan.
Nigba to n jẹwọ, Ayọbami sọ pe o pẹ ti oun ti mọ ẹni to ni ile naa, ati pe babalawo oun ni. O ni oṣooṣu loun maa n lọ sibẹ lati gba ọṣẹ awure to n ṣe fun oun. O ni nigba toun debẹ lati gba ti oṣu Karun-un, awọn araadugbo sọ f’oun pe baba naa ti ku, oun si pada sile pẹlu ibanujẹ.
Afurasi ọdaran yii sọ siwaju pe nigba ti oun pada sibẹ lọjọ keji, oun lọ sibi ti baba naa maa n fi kọkọrọ ile rẹ si, nigba toun wọle loun ko awọn ẹru yẹn pẹlu erongba lati ta a, ko too di pe ọwọ tẹ oun.
Adaralẹgbẹ ke si awọn araalu lati ma ṣe fi ọwọ yẹpẹrẹ mu eto aabo agbegbe wọn, o ni gbogbo bi Ayọbami ṣe ko ẹru ninu ile ọhun, to si fi ko o kọja laarin adugbo yẹn, ko sẹni to bi i leere ohunkohun. Afigba to pade awọn sifu difẹnsi ti wọn n lọ kaakiri ojuupopo lọna tawọn yẹn beere ibi to ti n bọ ati ẹni to ni ẹru ọwọ ẹ. Nigba to si n sọ kabakaba ni aṣiri tu pe ṣe lo ji awọn ẹru naa.