Adewale Adeoye
Ẹwọn oṣu marun-un pẹlu iṣẹ aṣekara adajọ ileejọ ‘Area Court’ kan, niluu Jos, Onidaajo Shawomi Bokkos, ju Abba Adam, ẹni ti wọn fẹsun kan pe o n lo orukọ ajọ to n gbogun ti gbigbe egboogi oloro nilẹ wa, ‘ National Drug Law Enforcement Agency’ (NDLEA) lati fi lu awọn eeyan ni jibiti kaakiri ilu, kọwọ too tẹ ẹ laipẹ yii.
Bakan naa ni wọn tun fẹsun iwa ole kan an pe o ti figba kan ja awọn araalu lole apo eedu, ewe agbo kan ti wọn n pe ni Moringa, ti apapọ owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna aadọta Naira, foonu igbalode ‘Hot-7’ kan ti owo rẹ to ẹgbẹrun lọna ogoji Naira, ọkada tiye owo rẹ to ẹgbẹrun din diẹ ni ẹẹdẹgbẹta Naira atawọn ohun mi-in.
Alaye ti olupẹjọ, Insipẹkitọ Monday Gokwat to foju Abba bale-ẹjọ naa ṣe ni pe ọjọ ti pẹ diẹ bayii ti Abba ti n lu awọn eeyan ni jibiti kaakiri aarin ilu, ko too di pe ọwọ tẹ ẹ laipẹ yii.
O ni awọn mẹta kan, Ahmed Yunusa, Abdullahi Haruna ati Magaji Adamu, ni wọn waa fẹjọ rẹ sun lọjo kẹjọ, oṣu Keji, ọdun 2023 yii pe Abba ji oniruuru ẹru awọn ti iye owo rẹ to ẹgbẹrun lọna ẹẹgbẹta Naira lọ.
Bakan naa la gbọ pe wọn ba kaadi idanimọ kan to jẹ ti ajọ NDLEA lọwọ rẹ lakooko ti wọn fọwọ ofin mu un. Oun paapaa si ti jẹwọ pe loootọ loun maa n lu awọn eeyan ni jibiti. Gbogbo awọn ẹsun ti wọn ka si Abba lẹsẹ yii ni wọn ni o lodi sofin, ti ijiya nla si wa fẹni to ba ṣẹ iru ẹṣẹ bẹẹ.
Loju-ẹṣẹ ti wọn ti ka awọn ẹsun naa si i lẹsẹ ni Abba paapaa ti n rawọ ẹbẹ si adajọ pe ko ṣiju aanu wo oun lori ọrọ naa.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Onidaajọ Bokkos ni ki wọn lọọ ju Abba sẹwọn oṣu marun-un, tabi ko san ẹgbẹrun lọna ogun Naira gẹgẹ bii owo itanran fohun to ṣe yii.