Ninu ofin eto idibo ọdun 1979, kinni kan wa nibẹ ti wọn fi ha a. Wọn ṣalaye ninu ofin naa pe ẹnikẹni ti ko ba sanwo ori ẹ ko lẹtọọ lati du ipo aarẹ, tabi ti gomina. Iyẹn ni pe ẹni yoowu ti yoo ba du ipo aarẹ, tabi ti yoo ba du ipo gomina, afi ko ni iwe owo-ori rẹ ko pe perepere, o kere tan, ko ti san owo-ori ọdun mẹta sẹyin lai yingin. Nitori bẹẹ, nigba ti ẹgbẹ GNPP ti fa Ibrahim Waziri kalẹ, ti NPN fa Shehu Shagari kalẹ, ti NPP fa Nnamdi Azikiwe kalẹ, ti PRP fa Aminu Kano kalẹ, ti UPN si fa Ọbafẹmi Awolọwọ kalẹ, gbogbo iwe wọn ni wọn ti ko ranṣẹ si ajọ to n ṣeto idibo naa, ohun ti wọn si n reti ni ki FEDECO to n ṣeto ibo kilia orukọ wọn lo ku, ki wọn si fọwọ si i pe awọn eeyan naa ti yege, ki wọn maa du ipo naa lọ. Bi wọn ba ti ṣe bẹẹ ni ijọba yoo ko ọlọpaa ti yoo maa ṣọ awọn ti wọn fẹẹ dupo aarẹ naa fun wọn.
FEDECO ti gba iwe wọn sọwọ ninu oṣu kẹta, ọdun 1979 yii, ipolongo ibo si ti n bọ, bo tilẹ jẹ pe wọn ṣi n reti aṣẹ igbẹyin lati ọdọ FEDECO. Afi lojiji ni kinni kan ṣẹlẹ, iroyin kan lo jẹ jade pe afaimọ ko ma jẹ FEDECO ti yọ orukọ Azikiwe ti ẹgbẹ NPP, ati Aminu Kano ti ẹgbẹ PRP, nitori ti wọn ko san owo-ori wọn. Alaga ajọ FEDECO to n ṣeto ibo naa, Ọgbẹni Michael Ani, lo kede bẹẹ funra rẹ. O ni loootọ ni iwe awọn to fẹẹ du ipo aarẹ lorukọ ẹgbẹ oṣelu gbogbo ti wa lọwọ awọn. Ṣugbọn ọrọ awọn meji kan ninu wọn ni wahala ninu. Wahala naa si ni ọrọ owo-ori wọn. Wọn ni ni ti Aminu Kano, ko si iwe ẹyọ kan bayii to fi han pe ọkunrin naa sanwo-ori lati igba to ti pẹ wa. Wọn ni ko fi iwe owo-ori ẹyọ kan bayii sinu iwe to ko ranṣẹ si awọn. Wọn ni bakan naa ni Azikiwe, bo tilẹ jẹ pe oun fi iwe owo-ori ranṣẹ, iwe naa ni bo ṣe jẹ.
Ninu iwe ti Azikiwe, o han pe oun naa ko sanwo-ori, afi ni asiko ti eto oṣelu fẹẹ bẹrẹ, nitori o jọ pe baba naa ti mọ pe awọn ẹgbẹ oloṣelu kan le fẹẹ fa oun kalẹ. Wọn ni ni ọdun 1978, lo sare sanwo-ori ti ọdun 1977 ati 1978, bẹẹ ohun ti ofin wi ni pe oloṣelu yoowu ti yoo ba du ipo aarẹ, ko gbọdọ jẹ ni asiko ti wọn ti bẹrẹ eto idibo ti yoo ṣẹṣẹ lọọ sare san owo-ori ọdun tabi iye igba to ba ti jẹ, wọn ni oloṣelu to ba lọọ sare san iru owo bẹẹ, saraa lo ṣe, nitori wọn yoo pada ja a bọ. Ohun ti Azikiwe si ṣe niyi, idi si ree ti ajọ FEDECO ko ṣe kọ orukọ awọn mejeeji wọle, tabi ki wọn ti i fọwọ si wọn, wọ ni ninu awọn mẹta ti awọn ti yẹ iwe wọn wo, Ọbafẹmi Awolọwọ nikan ni iwe rẹ pe pere, to san owo-ori rẹ ni asiko to yẹ, ati iye to yẹ ko san, ti ko si fi igba kan bọkan ninu, tabi ko purọ funjọba lori iye owo to n wọle fun un, tabi iye owo-ori to gbọdọ san.
Nigba ti Awolọwọ ko ti ni wahala, ko yẹ ki awọn oloṣelu to ku ti yoo du ipo aarẹ paapaa ni. Ṣugbọn ọrọ naa ko ri bẹẹ, ohun ti Azikiwe si ṣe ko ba ofin mu, ni FEDECO ba pariwo sita. Awolọwọ paapaa tilẹ sọrọ, o ni bi a ba fẹẹ sọ tootọ ati ododo, ẹni yoowu ti ko ba ti san owo-ori fun orilẹ-ede rẹ, ko lẹtọọ lẹni ti ẹnikẹni gbọdọ dibo fun, bẹẹ ni ko gbọdọ fa ara rẹ kalẹ pe ki ẹnikẹni dibo foun, ẹgbẹ oṣelu kan ko si gbọdọ fa tọhun kalẹ, nitori ohun ti eeyan fi n jẹ ọmọ orile-ede rẹ naa ni ko san owo-ori rẹ nigba to ba yẹ, bi tọhun ba ti n ṣiṣẹ, to si n pawo wọle. Awolọwọ ni ki i ṣe nitori pe oun fẹẹ du ipo aarẹ loun ti ṣe n san owo-ori oun lati ọjọ yii wa, ṣugbọn nitori pe oun mọ pe ojuṣe oun gẹgẹ bii ọmọ orilẹ-ede rere ni. Iyẹn naa loun si n ṣe, ti oun fi n sanwo-ori oun lai da a duro digba ti ibo ba n bọ, tabi ti oun ba mọ pe oun ni kinni kan ti oun fẹẹ gba lọwọ ijọba.
Ni ọjọ keji ni Aminu Kano ti jade ni tiẹ, niṣe lo fi ọfọ bọnu. O ni a ki i fi ọrọ papa lọ eku, bẹẹ ni ẹnikan ki i fi ọrọ odo lọ ẹkulu o, pe ko sẹni kan ti i beere owo posi lọwọ oku, ki FEDECO ma beere owo-ori kan lọwo toun o. Njẹ ki lo de ti ẹni to dagba to bẹẹ yẹn ko fi ni i sanwo-ori. Aminu Kano ni bi wọn ṣe n wo oun yii, iṣẹ ti oun n ṣe ko to iṣẹ ti eeyan le tori ẹ san owo-ori, pe owo oṣu oun tabi owo ti oun n pa lọdun ko pọ rara debii pe ẹnikan yoo beere owo-ori lọwọ oun. O ni lati ọdun 1976, oun ko gba owo kan teeyan le gba owo-ori lori ẹ, nitori owo ounjẹ nikan loun n ri ni toun. Aminu Kano ni ohun ti ofin sọ ni pe ki oun mu ninu owo ti oun ba pa, ki oun fi sanwo-ori, nigba ti oun ko si pa owo yii nkọ, ki waa ni ki oun ṣe. Akọwe ipolongo ẹgbẹ PRP, Uche Chukwumerije, lo gbe ọrọ naa jade lorukọ Aminu Kano ati ẹgbẹ wọn.
Inu awọn eeyan ko dun nigba ti wọn gbọ iru ọrọ yii lẹnu Aminu Kano ati awọn eeyan rẹ. Wọn ni ẹni ti yoo da aṣọ fun ni, ti ọrun rẹ ni eeyan yoo kọkọ wo, ẹni ti yoo tọju owo Naijiria, ti yoo si fi ẹsẹ orilẹ-ede naa le ọna okoowo ti yoo fi lowo lọwọ, ṣebi o yẹ ki tọhun ti maa ṣe iṣẹ gidi ni, ko si ti ni owo tirẹ, ko ma jẹ pe owo ti Naijiria ba pa yoo wọ tọhun loju, ṣugbọn ki eeyan kan wa ko ma ṣiṣẹ to to lati sanwo ori ninu ẹ, ko si ni oun fẹẹ ṣe olori ijọba Naijiria, njẹ owo ti Naijiria n pa ko ni i fẹju mọ tọhun bayii bi. Awọn ti wọn mọ Aminu Kano, tati awọn oloṣelu rẹ ninu PRP, ni ki i ṣe ọkunrin naa ni yoo ko owo jẹ. Wọn ni ṣebi o ti ṣe minisita titi, o si ti ṣe ọmọ ile-igbimọ aṣofin, fun bii ogun ọdun lo si fi wa to n ṣe minisita tabi ọmọ ile-igbimọ, to ba jẹ o fẹẹ ko owo ilu jẹ ni, igba naa ni yoo ti ko owo jẹ, gẹgẹ bi awọn ẹlẹgbẹ ẹ mi-in to jẹ iṣẹ ijọba nikan ni wọn ṣe, ti wọn si ti di olowo rẹpẹtẹ.
Ni wọn ba ṣaa fi Aminu Kano silẹ, wọn ni wọn yoo mọ ohun ti ijọba apapọ yoo ṣe fun un, ati pe idajọ ati aṣẹ ti ijọba ologun yii ba fun awọn lawọn yoo tẹ le ni tawọn. Ọrọ ko ri bẹẹ fun Azikiwe ni tirẹ, baba naa fa ibinu yọ gidi ni, o ni ki lo ṣe FEDECO ti wọn fẹẹ ba oun lorukọ daadaa ti oun ti n gbe bọ lati ọjọ yii jẹ, o ni o da bii pe awọn kan lo ṣan ọna lati kan oun labuku, ati lati gbe igi dina foun ki oun ma le du ipo aarẹ, nitori wọn ti mọ pe oun yoo wọle. O ni o dun oun pe iru Ani lawọn eeyan kan yoo maa lo lati fi ṣakoba fun oun, nitori eeyan daadaa loun ka Ani yii si. Kia lọkunrin naa ti pe awọn oniroyin jọ, nigba to si n bọ lati Onitsha wa si Eko, niṣe ni awọn ọmọlẹyin rẹ, ati awọn ti wọn jẹ aṣaaju ẹgbẹ oṣelu NPP n sare tẹle e kiri. Wọn ni awọn jẹrii ọga awọn, ki i ṣe owo-ori ni ko ni i san, abi eelo lowo-ori ọhun gan-an.
Ọrọ ti Azikiwe sọ naa bi Ani ninu. O ni bi nnkan ṣe wa yii, afaimọ ko ma jẹ ile-ẹjọ ti Azikiwe n leri yẹn gan-an ni ko gba lọ, bo ba si de ile-ẹjọ, awọn naa yoo pade rẹ nibẹ, ki awọn jọ lọọ koju adajọ, ki wọn si tumọ ofin yii fawọn. O ni ofin to wa lọwọ awọn sọ pe eeyan kan to fẹẹ du ipo oṣelu ko gbọdọ lọọ sanwo-ori rẹ ti ọdun to ti kọja ni ọdun to jẹ ọdun ti yoo du ipo, o ti gbọdọ sanwo ni asiko ti ko si ibo, nigba ti akoko owo-ori rẹ ba pe lati san an. Eyi yoo fi tọhun han pe aṣaaju rere ni, ko ni i jẹ nitori ti ibo n bọ ni iru ẹni bẹẹ ṣe ṣẹṣẹ n lọọ sare sanwo. Ani ni ohun ti ofin sọ niyi. Ṣugbọn Azikiwe ko tẹle eyi, owo-ori ọdun 1977, ati ti 1978 to fẹẹ san, ni ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu kin-in-ni, ọdun 1979, lo ṣẹṣẹ lọọ san an, ohun ti risiiti to mu wa sọ niyi. Bawo ni yoo waa ṣe fi ikanra mọ oun ti yoo ni ẹni kan lo n lo oun bi oun ṣe to yi lati ba orukọ oun jẹ, nigba to ṣe pe oun Azikiwe funra ẹ ni ko ṣe ojuṣe to yẹ ko ṣe.
N ni Azikiwe ba binu o, o ni oun n lọ sile-ẹjọ dandan ni.