Baalẹ meji dero ẹwọn, ‘ilẹ ooṣa’ ni wọn ji ta

Faith Adebọla

Baalẹ, ọkọ ilu meji kan, Alagba Ọlalekan Ọdẹmuyiwa, ẹni ọdun mejidinlọgọta, ti i ṣe Baalẹ abule Agejo, ati Ọgbẹni Oluwaṣẹgun Konigbagbe, ẹni aadọta ọdun, toun jẹ Baalẹ Abule Ake ti mejeeji wa nijọba ibilẹ Ọbafẹmi Owode, nipinlẹ Ogun, ti n fẹnu fẹra bii abẹbẹ ni keremọnje bayii. Ohun to gbe wọn debẹ ni pe wọn wọnu ilẹ ijọba to jẹ ti ileeṣẹ redio ipinlẹ Ogun, Ogun State Broadcasting Corporation (OGBC), wọn bu apa kan ilẹ ọhun ta fawọn onibaara kan, wọn si tun bẹrẹ si i kọle sawọn apa miiran.

Awọn mẹrin mi-in ti wọn jọ lọwọ ninu aṣa palapala ọhun ni Wasiu Ogunṣina, ẹni ọdun mọkanlelaaadọta, Babatunde Ọdẹmuyiwa, ẹni ọdun mọkanlelọgọta, Kabiru Ọlafẹnwa, ati Dare Awodele.

Alaye ti Agbefọba, Inpẹkitọ Adekanmi Adeusi, ṣe niwaju ile-ẹjọ Majisireeti kan to fikalẹ siluu Abẹokuta lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Keje yii, lasiko tawọn afurasi ọdaran naa n fara han fungba akọkọ ni pe atawọn to jẹ baalẹ laarin afurasi yii, atawọn ti ki i ṣe baalẹ, o ni iṣẹ ajagungbalẹ ni wọn n ṣe rẹbutu, iwa agba-lọwọ-merii, ati ilaalaṣi ọmọlakeji ẹni lori dukia rẹ lo kun ọwọ gbogbo wọn.

O ni iwa irufin yii naa lo mu kawọn agbofinro lọọ fi pampẹ gbe wọn lọjọ kọkandinlogun, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, nigba tawọn alaṣẹ ileeṣẹ redio OGBC kọwe ẹsun ṣọwọ si ọfiisi Akọwe ijọba ipinlẹ Ogun nipa bi awọn atilaawi yii ṣe wọnu ilẹ onilẹ, ti wọn si n ta a, ti wọn n fowo ẹ ṣara rindin.

O lẹsun ti wọn fi kan wọn ọhun ta ko iwe ofin iwa ọdaran nipinlẹ Ogun, ati pe ijọba ipinlẹ ọhun ko fẹẹ gbooorun ẹnikẹni to ba n huwa ajagungbalẹ rara, mimu lawọn n fọwọ ṣinkun ofin mu ẹnikẹni to ba lọ n ṣe bii akilapa lori dukia ẹni ẹlẹni.

Nigba ti wọn beere lọwọ awọn afurasi naa boya wọn jẹbi tabi wọn ko jẹbi, gbogbo wọn lawọn ko jẹbi rara.

Eyi lo mu ki Onidaajọ, Ọṣibajo paṣẹ pe ki wọn rọ gbogbo wọn da sẹwọn na. Ọgba ẹwọn to wa lagbegbe Ibara, ni ki wọn ko wọn lọ, ibẹ ni wọn yoo si wa fun saa ọgbọn ọjọ, lati faaye silẹ ki wọn gbe faili ẹjọ lọ sọfiisi ajọ to n gba awọn adajọ nimọran.

Adajọ naa ni oun ko ti i lanfaani lati gba beeli wọn.

Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ to kan si ọjọ kẹẹẹdogun, oṣu Kẹjọ, ọdun yii.

Leave a Reply