Ibrahim Alagunmu
Ọgbẹni Ahmed Atọlagbe, ẹni ọdun marunlelogoji, ti i ṣe baba Abdulwahab, ẹni ọdun meje, ati Roqeeb, ẹni ọdun mẹsan-an ti fẹnsi otẹẹli kan wo pa lasiko ti wọn n sun lọwọ ninu yara wọn lọjọ kejilelogun, oṣu Keje, to kọja yii niluu Ikorodu, nipinlẹ Eko, ti ni kijọba ba oun da sọrọ naa, ki wọn fi ẹni to ni otẹẹli naa jofin.
Ọgbẹni Atọlagbe, to jẹ ọmọ bibi ipinlẹ Kwara, to n fi ẹdun ọkan rẹ han ṣalaye pe ibi iṣẹ fọniṣọ toun n ṣe lagbegbe Irawọ ni oun wa lọjọ tiṣẹlẹ buruku yii waye. O ni lọjọ naa loun gba ipe pajawiri pe koun maa sare bọ nile, sugbọn nigba ti oun dele loun ri i pe fẹnsi otẹẹli ti wo pa awọn ọmọ oun latara agbara to n ya lu fẹnsi naa. O ni awọn ọmọ meji lo ku, ẹgbọn wọn agba naa fara pa, iṣẹlẹ yii si pọ ju fun iyawo oun, eyi to mu ko daku nileewosan lo gbe e nija.
Atọlagbe ni oun kọkọ mu ẹsun naa lọ si agọ ọlọpaa Owutu, ti wọn si pada gbe ẹjọ rẹ lọ si ẹka ti wọn ti n ṣe iwadii iwa ọdaran ni Panti, Yaba.
Baba awọn ọmọ yii ni oun ti n gbọ pe wọn o fẹ ki ẹjọ naa de kootu, ṣugbọn oun beere fun idajọ ododo lori iku awọn ọmọ oun.
Ajafẹtọọ-ọmọniyan nni, Fẹmi Falana (SAN), sọ ninu ifọrọwerọ to ṣe pẹlu iwe iroyin PUNCH, pe kijọba ipinlẹ naa ṣe iwadii to tọ lori iṣẹlẹ yii, ki wọn si ṣayẹwo ipo ti otẹẹli ọhun wa. O fi kun un pe kijọba tete gbọ ẹjọ naa, ki wọn si ṣe ẹkunrẹrẹ iwadii lori ohun to ṣokunfa bi fẹnsi naa ṣe wo, ki wọn si ri i daju pe idajọ ododo waye lori awọn ọmọ to pade iku ojiji lasiko ti wọn n sun lọwọ.
A gbọ pe ẹni to ni otẹẹli ọhun ṣi wa lahaamọ ọlọpaa, bo tilẹ jẹ pe o ni oun yoo fun mọlẹbi Atọlagbe lowo, oun yoo si tun kọ ile miiran fun un, ṣugbọn Atọlagbe ni oun ko fẹ, idajọ ododo loun fẹ.