Faith Adebọla
Bi gbogbo nnkan ba lọ bi wọn ṣe ṣeto rẹ, Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ yii, ni ọkan ninu awọn adẹrin-in-poṣonu ilẹ wa ti wọn fẹsun ṣiṣe ọmọ kekere baṣubasu, James Omiyinka, ti gbogbo eeyan tun mọ si Bbaba Ijẹṣa yoo foju bale-ẹjọ.
Ile-ẹjọ Majisreeti Kootu Kin-in-ni, to wa ni Yaba, nipinlẹ Eko, ni ireti wa pe Omiyinka yoo ti duro sọ tẹnu rẹ niwaju adajọ, nibi ti wọn yoo ti sọ boya o jare tabi o jẹbi ẹsun ti wọn fi kan an.
Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa nipinlẹ Eko, Ọmọọba Muyiwa Adejọbi, fidi iroyin yii mulẹ nigba ti akọroyin wa pe e laaarọ yii. O ni loootọ ni Baba Ijẹṣa yoo foju bale-ẹjọ laago mẹsan-an aarọ Ọjọruu, Wẹsidee, yii.
Tẹ o ba gbagbe, lati inu oṣu kerin ti wọn ti ni ọkunrin naa fẹẹ fipa ba ọmọ ti ko ju ọdun mẹrinla lọ lo pọ, ti wọn si tiẹ ni o ti ba ọmọ naa lo pọ lọmọ ọdun meje ni wahala ti de ba oṣere yii, ti wọn si fọlọpaa mu un.
Latigba na lo ti wa lagọọ ọlọpaa, pabo si ni gbogbo akitiyan lati gba beelu rẹ ja si nitori ede aiyede to wa laarin awọn lọọya rẹ ati ileeṣẹ ọlọpaa.