Baba Mohbad figbe ta: Ẹyin ọmọ Naijiria, ẹ ṣaanu mi, mo nilo owo lati fi ṣayẹwo ẹjẹ fọmọ oloogbe

 Adewale Adeoye

‘Ẹyin ẹlẹyinju aanu ọmọ orilẹ-ede yii, ọrọ mi ko gbọdọ su yin rara, paapaa ju lọ lasiko yii, gbogbo eeyan lo mọ pe mi o lowo lọwọ lati fi ṣayẹwo ẹjẹ si Liam, ọmọ kan ṣoṣo tiyawo oloogbe loun bi fun un. Mo gbọdọ ṣayẹwo ẹjẹ ọhun fun ọmọ naa lọna meji ọtọọtọ, ki n le lẹrii to daju pe loootọ ọmọ-ọmọ mi ni Wunmi gbe lọwọ, bi ki i baa ṣe ẹjẹ mi lọmọ ọhun, n ko nilo lati maa ṣetọju ọmọ ọlọmọ mọ ohun to ṣẹlẹ si mi yii rara. Ohun kan ṣoṣo ti mo n beere fun lọwọ gbogbo ọmọ orilẹ-ede yii ni pe ki wọn dide iranlọwọ owo fun mi lati ṣayẹwo ẹjẹ f’ọmọ naa, ki n le mọ inu odo ti mo fẹẹ da ọrunla si’’.

Eyi lọrọ to n jade lẹnu Alagba Joseph Alọba ti i ṣe baba gbajumọ olorin hipọọpu nni, Oloogbe Ilerioluwa Alọba, ẹni tawọn eeyan mọ si Mohbad.

Aipẹ yii ni baba oloogbe yii ṣe ifọrọwero kan pẹlu gbajumọ sọrọsọrọ lori redio, Ọgbẹni Hamsat, to si ṣalaye ohun to n fẹ lori iku ọmọ rẹ. Ninu alaye ti baba naa ṣe lori ẹrọ ayelujara lo ti rọ gbogbo awọn alaṣẹ ijọba orilẹ-ede wa pe ki wọn ma ṣe wo oun niran rara lori iku ọmọ oun yii, ki wọn dide iranlọwọ gidi soun lati fọwọ ofin mu gbogbo awọn to lọwọ ninu iku oloogbe naa, ki wọn si fiya gidi jẹ gbogbo wọn. Bakan naa lo rawọ ẹbẹ sawọn ẹlẹyinju aanu ti wọn jẹ ọmọ ilẹ wa nile, loko ati lẹyin odi, pe, ki wọn dide iranlọwọ owo soun lati le ṣayẹwo ẹjẹ fọmọ ti oloogbe fi saye lọ koun le mọ eyi to jẹ ootọ nipa ọrọ ọmọ naa bayii.

Bẹ o ba gbagbe, Alagba Alọba ti i ṣe baba oloogbe yii ti figba kan sọ ọ ni kootu to wa n’Ita Ẹlẹwa, niluu Ikorodu, ipinlẹ Eko, nibi ti wọn ti n gbẹjọ lori iku ọmọ rẹ pe aimọye igba loun ti ba ọmọ oun ti i ṣe oloogbe ati iyawo rẹ pari ija to ni i ṣe pẹlu aifọkan tan ara ẹni ninu ile.

Baba ọhun soju abẹ nikoo niṣoju gbogbo eeyan ti wọn wa ni kootu lọjọ naa pe aimọye igba ni Wunmi ti i ṣe iyawo oloogbe maa binu jade kuro ninu ile ọkọ rẹ, ta a si lọ lai boju wẹyin fun ọpọ ọjọ ati ọsẹ.

O fi kun ọrọ rẹ pe ọjọ kan wa tiyawo oloogbe yii foogun oorun sinu ounjẹ ọkọ rẹ nitori ko le raaye rin irin ẹsẹ rẹ bo ṣe wu u. Gbogbo ọrọ yii ni baba naa ro papọ to fi sọ pe afigba tawọn ba ṣayẹwo ẹjẹ fọmọ oloogbe naa, ti esi ayẹwo ọhun si fidi ootọ mulẹ pe oloogbe lo lọmọ ọwọ iyawo rẹ loun maa too gba Liam gẹgẹ bii ọmọọmọ oun.

Ẹbẹ kan ti alagba ọhun n bẹ bayii ni pe kawọn eeyan ṣaanu oun nipa ayẹwo ọhun, ki wọn dide iranlọwọ owo s’oun lati ṣayẹwo naa.

 

Leave a Reply