“Baba nla ole ati akowojẹ ni yin,” PDP lo sọ bẹẹ fawọn APC

 

Ko si ẹgbẹ oṣelu kan to jẹ ẹgbẹ awọn ole ati akowo-ilu-jẹ to ju ẹgbe APC to wa ni Naijiria yii lọ. Alukoro ẹgbẹ oṣelu PDP, Kọla Ologbondiyan, lo n bọ bẹẹ; to ni ko tun si orirun tabi ikorita ti iwa ibajẹ pin si ju inu ẹgbẹ APC lọ, nitori lojoojumọ ni iwa ibajẹ wọn n gbilẹ si i.

Atẹjade kan to gbe jade lanaa lo ti n sọ gbogbo eyi, pẹlu alaye pe oórùn iwa ibajẹ to n jade lati inu iwadii ileeṣẹ NDDC (Niger Delta Development Commission) ti wọn n ṣe lọwọ yii ti fihan pe bi eeyan ba ti ri awọn ọmọ APC, ko ma wo wọn lẹẹmeji, ko ti mọ pe onibajẹ ni gbogbo wọn. Ologbondiyan ni awọn ti gbọ ninu ẹgbẹ tawọn pe awọn agbaagba APC  fẹẹ pa iwadii ti won n ṣe lọwọ lori ọọ ileeṣẹ NDDC yii mọlẹ. Bẹẹ nibẹ ni wọn ti fẹsun kan minisita Akpabio pe o kowo jẹ, ti Akpabio fẹsun kan awọn aṣofin ti wọn n wadii ọrọ yii  pe awọn naa kowo jẹ, ti wọn si ni ki olori ileeṣẹ NDDC naa waa ṣalaye bi ọrọ ti ri to jẹ niṣe loun digbo lulẹ, to daku. Ohun to jẹ ki awọn PDP sọ pe agbada iwa ibajẹ wa lọrun wọn ninu APC niyẹn.

Bẹẹ, awọn APC ni wọn tanna wa ọrọ buruku yii o. Awọn ni wọn kọkọ sọ pe gbogbo iwa ibajẹ to n ṣẹlẹ ni ileeṣẹ NDDC yi, awọn PDP lo ti bẹrẹ ẹ, ohun ti awọn ba nilẹ ni. Bẹẹ lawọn kan ninu awọn aṣaaju APC yii sọ pe awọn ti wọn ti inu PDP wa ni wọn n huwa ibajẹ to pọ ju lọ ninu ẹgbẹ awọn. Ohun to bi PDP ninu ree, ni wọn ba ni ki alukoro wọn, iyẹn Ologbondiyan po’kọ ibanujẹ fun wọn mu.

 

Leave a Reply