Baba Ọlọfaana ti tọrọ aforiji lọwọ awọn oṣere tiata obinrin fun ọrọ to sọ, paapaa fun bo ṣe ni pupọ ninu awọn onitiata obinrin ni wọn maa n ba ni ibalopọ lagbo oṣere. Ṣe ẹ ranti pe Baba naa ni ko jẹ tuntun pe ibalopọ n waye laarin awọn oṣere tiata nigba to n ba ALAROYE sọrọ ni kootu ti wọn ti gbọ ẹjọ Baba Ijẹṣa lọsẹ to kọja.
Ninu fidio kan to fi lede, Olofaana tọrọ aforiji, o sọ pe kawọn eeyan ma ṣi oun gbọ o, oun ko ṣegbe lẹyin ki wọn maa fi ipa ba obinrin tabi ọmọde lo pọ.
O ni ara lo ta oun to mu ki oun sọ ohun toun sọ lọgba kootu Ikẹja yẹn, ohun toun si ni lọkan kọ lawọn eeyan n tumọ ọrọ naa si.
O fi kun pe, “Ẹma binu ana, paapaa ẹyin obinrin ti ẹ jẹ iya wa nidii iṣẹ tiata.”
Agba ọjẹ naa ṣọ siwaju si pe ki i ṣe aṣa awọn onitiata ni lati maa fi ọwọ pa obinrin lara lọna aitọ nitori ẹṣẹ ni niwaju Ọlọrun, bẹẹ lo si ṣalaye pe awọn obinrin onitiata ki i ṣe aṣẹwo o, o ni kawọn ọkunrin ti ibalopọ lọna aitọ ba ti wọ lẹwu tete yaa mọ bi wọn ṣe maa jawọ nibẹ.