Ọlawale Ajao, Ibadan
Gbajumọ ajinhinrere nni, ẹni to tun jẹ oludasilẹ ijọ CAC Oke Agbara, to wa laduugbo Aṣi, ni Bodija, n’Ibadan, Wolii Micheal Ojo Ọlọwẹẹrẹ, tọpọ eeyan tun mọ si Baba Ọlọwẹrẹ, ti dagbere faye.
Ọjọruu, Wẹsidee, ọsẹ, ọjọ karun-un, oṣu Keje, ọdun 2023 yii, ni Wolii naa dagbere faye nile ẹ to wa ni Aṣi, niluu Ibadan, nitosi Bodija.
Adẹrin-in-poṣonnu nni, Wolii Arole, naa fidi iroyin yii mulẹ loju opo ikanni ayelujara rẹ nigba to n ṣedaro Baba Ọlọwẹrẹ, tọpọ eeyan tun mọ si Baba Automatic.
O ni inu oun dun pe oun gba ami ororo wolii yii nigba to wa laye.
Bo tlẹ jẹ pe ko sẹni to mọ pato ọdun naa, lọjọ kẹsan-an, oṣu kẹsan-an, ni gbogbo aye gba pe wọn bi Baba Ọlọwẹrẹ, o si jẹ ọkan ninu awọn wolii ti Wolii Ayọ Babalọla ta ami ororo le lori.
Lọdun 1978 lo da ijọ CAC Oke-Imọlẹ silẹ, o si lewaju ṣọọṣi yii niluu Ibadan titi to fi dagbere faye.