Ọlawale Ajao, Ibadan
Ọkunrin to ṣe asia orileede wa, Naijiria, AlagbaTaiwo Akinkunmi (O.FR), ti dagbere faye lẹni ọdun mẹtadinlaaadọrun-un.
Ọmọ rẹ, Akinkunmi Akinwunmi Samuel, lo sọ eyi di mimọ loju opo ikanni Fesibuuku rẹ, nibi ti ṣedaro baba to bi i lọmọ ọhun.
Ọjọ kẹwaa, oṣu karun-un, ọdun 1936, ni wọn bi i. Iyẹn ni pe ọdun mẹtadinlaaadọrun-un (87) ni baba naa lo loke eepẹ ko too dagbere faye
Bo tilẹ jẹ pe ilu Ibadan ni baba yii n gbe, ọmọ bibi ilu Owu, nipinlẹ Ogun, ni i ṣe.
O lọ sileewe Baptist Day fun ẹkọ alakọọbẹrẹ rẹ, ati Ibadan Grammar School, fun ẹkọ girama rẹ.
Akinkunmi gba iṣẹ ijọba ni sẹkiteriati Ibadan, lẹyin to ṣiṣẹ diẹ lo si lọ siluu Norway, nibi to ti kẹkọọ nipa iṣẹ agbẹ.
Ilu Oyinbo lo wa to fi ri ikede kan pe wọn n wa ẹni ti yoo ṣe asia ti Naijiria yoo maa lo ni ipalẹmọ fun ominira orileede yii.
Ọkunrin ọmọ bibi ilu Owu yii naa wa lara ogunlọgọ eeyan to dabaa iru asia ti Naijiria le maa lo, tiẹ ni wọn si mu ninu awọn eeyan bii ẹgbẹrun meji to dan kinni ọhun wo.
Aworan to kọkọ ṣe ni awọ funfun laarin pẹlu awọ eweko meji, ti itansan oorun si wa nibẹ, ṣugbọn awọn igbimọ to ṣayẹwo fun un lo yọ itansan oorun yii danu.
Idi ti wọn ṣe mu ti Akinkunmi ni pe o ṣakotan apejuwe ilẹ wa. Awọ eweko duro fun awọn igbo ati ohun alumọọni to sodo silẹ wa, ti awọ funfun si duro fun alaafia.
Ọjọ kin-in-ni, oṣu Kẹwaa, ọdun 1960, ni wọn ta asia yii nibi ayẹyẹ ominira ilẹ yii, dipo asia ilẹ Gẹẹsi to jẹ tijọba awọn Oyinbo amunisin.
Ọgọrun-un pọun (100€) nijọba fun Akinkunmi fún iṣẹ ribiribi naa, ti ijọba aarẹ tẹlẹ, Goodluck Jonathan, si fi ami-ẹyẹ MON da a lọla lọdun 2014, lẹyin ti ileegbimọ aṣofin ipinlẹ Ọyọ ti kọkọ fun un lami-ẹyẹ lọdun 2013, lasiko ijọba Gomina Abiọla Ajimọbi.