Baba yii yoo farugbo ara ṣẹwọn o, egboogi oloro rẹpẹtẹ ni wọn ka mọ ọn lọwọ l’Ekiti

Taofeek Surdiq, Ado Ekiti

Ọdọ ajọ to n gbogun ti gbigbe ati lilo egboogi oloro laarin ilu ‘National Drug Law Enforcement Agency’ (NDLEA), ẹka tipinlẹ Ekiti, ni baba agbalagba kan, Ọgbẹni Audu Jubril, ẹni ọdun marundinlọgọrin wa bayii, ẹsun pe, o n ṣowo egbogi oloro laarin ilu ni wọn fi kan an.

Ọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un, ọdun 2024 yii, lọwọ awọn oṣiṣẹ ajọ ọhun tẹ Audu Jubril to n ṣowo Igbo niluu kekere kan ti wọn n pe ni Oke-Asa, ni Ijero Ekiti, nipinlẹ Ekiti. Awọn araalu ọhun ti wọn mọ nipa iṣẹ ti ko bofin mu ti baba naa n ṣe ni wọn lọọ fọrọ rẹ to awọn agbofinro leti, tawọn yẹn si waa fọwọ ofin mu un.

ALAROYE gbo pe o ti pẹ ti Audu ti n ṣowo egboogi oloro, ṣugbọn tọwọ palaba rẹ segi lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ kẹwaa, oṣu Karun-un, ọdun yii.

Alukoro ajọ NDLEA, Ọgbẹni Fẹmi Babafẹmi, to fidi iṣẹlẹ ọhun mulẹ fawọn oniroyin lọjọ Aiku, Sannde, ọjọ kejila, oṣu Karun-un, ọdun yii, sọ pe gbogbo ohun to ba gba pata lawọn maa fun un lati kapa awọn oniṣẹ ibi naa laarin ilu, ati pe lẹyin iwadii lawọn maa foju rẹ bale-ẹjọ.

Leave a Reply