Babalawo lo ni ka lọọ wa ori eeyan tutu wa ta a fi pa pasitọ yii sinu oko ẹ-Musa

Oluṣẹyẹ Iyiade, Akurẹ

Ojisẹ Ọlọrun kan, Pasitọ Dada Itọpa, lo ti kagbako iku airotẹlẹ latọwọ awọn lebira meji to bẹ lọwẹ lati lọọ ba a ṣiṣẹ ninu oko rẹ to wa labule Ebira, Ipele, n’ijọba ibilẹ Ọwọ.

ALAROYE gbọ lati ẹnu Alukoro ileeṣẹ ọlọpaa ipinlẹ Ondo, Abilekọ Funmilayọ Ọdunlami, pe iṣẹ lebira (alagbaro) lawọn afurasi mejeeji, Muhammed Musa ẹni ọgbọn ọdun, ati Omatai, yan laayo labule ọhun.

O ni ọjọ Aje, Mọnde, ọjọ keje, oṣu Kẹjọ yii, ni Pasitọ Dada ati iyawo rẹ, Bọsẹ Dada, ko awọn lebira mejeeji lọ sinu oko wọn lati lọọ ba wọn ṣiṣẹ pẹlu adehun lati san ẹgbẹrun mọkanla Naira fun wọn lẹyin ti wọn ba pari oko ti wọn fẹẹ lọọ ju.

Bi wọn ṣe de inu oko lọhun-un ni Omatai bẹ ọga to ko wọn lọ, iyẹn Pasitọ Dada, pe ko sare ya oun ladaa to wa lọwọ rẹ, nitori oun fẹẹ wo bi ada naa ṣe mu si.

Baba ẹni ọdun marundinlaaadọta ọhun ko kuku mọ ero to wa lọkan awọn alagbaṣe rẹ, bẹẹ ni ko fura rara pe wọn tilẹ le ronu ohun ti ko dara si oun, idi ree to fi yọnda ada naa fun Omatai loju-ẹsẹ, laimọ pe ohun to le lẹyin loun ṣe.

Bi ada ṣe tẹ ọmọkunrin yii lọwọ tan, ọga rẹ lo fi doju kọ, to si n ṣa a bii igba tawọn alapata ba n ṣa ori maaluu.

Ko si obinrin gidi ti yoo kawọ gbera niru asiko yii ti ko ni i tara, ko si wa gbogbo ọna lati doola ẹmi ọkọ rẹ, eyi ni Bọsẹ n gbiyanju lati ṣe nigba ti Musa tun kọju ija si oun naa, to n si n fi ada ṣa obinrin naa lori kikan kikan.

Bayii ni Musa ati ọrẹ rẹ ṣe pa ọga wọn nipakupa sinu oko, ṣugbọn ti ori pada ko iyawo ọkunrin naa yọ, bo tilẹ jẹ pe ẹsẹ-kan-aye, ẹsẹ-kan-ọrun lo wa lọsibitu to ti n gba itọju di ba a ṣe n sọ yii.

Lẹyin-o-rẹyin, ọwọ awọn ọlọpaa pada tẹ Musa, oun lo si waa ṣalaye idi ti wọn fi pa Pasitọ Dada nipakupa fawọn agbofinro.

Musa jẹwọ pe awọn pa ọga awọn lẹyin ti babalawo kan to filu Ipele ṣe ibugbe ran awọn lati lọọ wa ori eeyan tutu wa.

Ọdunlami ni iwadii awọn ṣi n tẹsiwaju lori bi ọwọ ṣe fẹẹ tẹ babalawo naa ko le waa sọ ti ẹnu rẹ.

 

Leave a Reply