Monisọla Saka
Awọn alalṣẹ olori banki apapọ orilẹ-ede yii, Central Bank of Nigeria (CBN), ti kede pe awọn ti wọgi le gbedeke ti wọn fun nina owo Naira atijọ titi di igba tẹni kan o le sọ. Wọn ni ki awọn araalu si maa na owo naa lọ lati fi ṣe kara-kata wọn.
Lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọjọ kẹrinla, oṣu Kọkanla, ọdun yii, ni Isa AbdulMumin, ti i ṣe agbẹnusọ banki apapọ wa lori iroyin fọrọ naa lede ninu atẹjade kan.
Nibẹ ni wọn ti fidi ẹ mulẹ pe gbogbo igbesẹ lawọn n gbe lati jẹ ki ọwọ kan ọwọ pẹlu ileeṣẹ tọrọ kan lori bi wọn yoo ṣe fagi le idajọ kootu to fun wọn ni gbedeke igba ti wọn yoo nawo naa da.
Wọn ni igbesẹ yii wa ni ibamu pẹlu bi wọn ṣe n ṣe lawọn orilẹ-ede agbaye, ati lati dena iru awọn ijamba ati inira to waye lasiko ti wọn n paarọ owo Naira nibẹrẹ ọdun yii.
Igba kẹta ree ti banki to ga ju lọ naa yoo fi atẹjade lede lori owo Naira atijọ ni nina. Nibẹrẹ oṣu Kọkanla yii, ni wọn fidi ẹ mulẹ pe ko si nnkan to n jẹ ọwọngogo owo Naira nita. Ati pe gbogbo owo Naira pata, yala ti atijọ ni abi eyi ti wọn ṣẹṣẹ tẹ, lo jẹ itẹwọgba nibikibi, ẹnikẹni ko si gbọdọ kọ ọ.
Ninu atẹjade yii ni wọn ti ni, “Lai si kọnu-n-kọhọ kankan, banki apapọ ilẹ wa n mu erongba wọn wa si etiigbọ gbogbo araalu lori ati sun nina igba, ẹẹdẹgbẹta ati ẹgbẹrun Naira atijọ siwaju si i titi digba ti a ko le sọ.
“Eyi wa ni ibamu pẹlu bi wọn ṣe n ṣe lawọn orilẹ-ede agbaye. Nitori naa, gbogbo owo Naira to jade ni ibamu pẹlu iwe ofin banki apapọ wa ti ọdun 2007, ni yoo tubọ maa jẹ itẹwọgba titi lae, koda kọja ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila, ọdun yii, ti wọn fi ṣe gbedeke rẹ tẹlẹ.
“Gbogbo ileeṣẹ tọrọ kan ni banki apapọ n ṣiṣẹ pẹlu ẹ, lojuna ati le gbegi le idajọ ile-ẹjọ to ga ju nilẹ wa lori ọrọ owo yii. Bakan naa, gbogbo ẹka banki apapọ to wa jake-jado orilẹ-ede yii ni yoo tubọ maa gba a, ti wọn yoo si maa fi owo Naira atijọ ati eyi ti wọn tun tẹ sanwo jade.
“A wa n rọ gbogbo araalu lati tubọ maa gba awọn owo Naira mejeeji yii nidii iṣẹ oojọ wọn, ki wọn si tọju awọn owo naa daadaa lati le daabo bo o, ko si le tubọ pẹ si i. Bakan naa la tun n rọ awọn araalu lati maa ṣamulo eto owo sisan ori ẹrọ ayelujara fun kara-kata, ati iṣẹ oojọ wọn gbogbo”.
Banki apapọ ilẹ wa ṣe eleyii latari idajọ ile-ẹjọ to ga ju lọ nilẹ wa, Supreme Court, ti wọn ṣe ninu oṣu Kẹta, ọdun yii, pe ni kete to ba ti di ọjọ to kẹyin ninu ọdun 2023 yii, iyẹn ọjọ kọkanlelọgbọn, oṣu Kejila, ni wọn yoo ko owo Naira atijọ nilẹ, ti ko si ni i jẹ itẹwọgba nibikibi mọ.