Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Afaimọ ki iwa ti ọmọkunrin ẹni ọdun mejilelaaadọta kan, Oluṣẹgun Ayẹni, hu ma sọ ọ dero ẹwọn pẹlu bawọn ọlọpaa ṣe wọ ọ lọ sile-ẹjọ lori ẹsun pe o lọọ ji batiri ọkọ kan gbe.
Gẹgẹ bi awọn ọlọpaa ṣe sọ, ẹsun kan ṣoṣo to ni i ṣe pẹlu ole jija ni wọn tori ẹ wọ ọmọkunrin naa wa sile-ẹjọ.
Agbefọba, Isipẹkitọ Akinwale Oriyọmi, sọ fun ile-ẹjọ pe Ayẹni ṣẹ ẹsẹ naa lọjọ kẹfa, oṣu Kẹta, ọdun yii, ni deede aago mẹwaa aabọ alẹ, ni agbegbe opopona to lọ lati ilu Ado-Ekiti si Iyin-Ekiti.
Oriyọmi sọ pe ọdaran naa ji batiri ọkọ kan ti iye owo rẹ jẹ ẹgbẹrun lọna mejidinlogbon Naira ati jala epo bẹntiroolu mẹrin ti iye rẹ to ẹgbẹrun lọna mẹrin, to jẹ ti Ọgbẹni Festus Afẹ.
Iwa yii ni wọn sọ pe o lodi sofin ole jija ti ipinlẹ Ekiti ṣe lọdun 2021.
Ṣugbọn agbẹjọro ọdaran naa, Ọgbẹni Emmanuel Sunmọnu, bẹ ile-ẹjọ pe ko faaye beeli silẹ fun onibara oun, pẹlu bo ṣe sọ pe oun ko jẹbi ẹsun naa. O ṣeleri pe ko ni sa ti wọn ba fun un ni beeli.
Bakan naa ni agbefọba tọrọ aaye ranpẹ lọwọ ile-ẹjọ naa pe ki oun le ri aaye lati ṣayẹwo si faili ẹjọ naa, ati ki oun le ko awọn ẹlẹrii oun jọ lati waa jẹrii lakoko ti igbẹjọ naa ba bẹrẹ.
Ṣugbọn, adajọ ile-ẹjọ naa, Onidaajọ Bankọle Oluwasanmi, gba beeli ọdaran naa pẹlu oniduuro kan. O sọ pe oniduuro naa gbọdọ mu fọto pelebe meji silẹ, ati pe o gbọdọ jẹ ẹni to n gbe ni agbegbe ile-ẹjọ naa.
Lẹyin eyi lo sun igbẹjọ mi-in si ọjọ kejilelogun, oṣu Kẹta, ọdun yii.