Niṣe ni mo n bẹ Safu ko ma sọ ọrọ ilẹ ẹ ti a lọọ ra fẹni kan, mo ni ko fun mi laaye ki n sọ fun wọn nikọọkan. Ẹni kan ṣoṣo ti n ko le gbe iru nnkan bẹẹ yẹn gba ẹyin ẹ kọja naa ni Sẹki, ohun to si fa a naa ni pe ọrọ emi ati oun naa ye ara wa daadaa ju ti ẹnikẹni lọ. Oun naa ti n kọle tiẹ lọwọ, awọn aiyaara iyaale ẹ ati ọrọ Korona ti ko jẹ ki ọja lọ deede yii lo jẹ ko dawọ duro diẹ nibẹ, ọwọ ẹ ki i kuro nibẹ rara. Nitori mo fun un lowo diẹ ki oun naa lọọ sare ṣe nnkan kan nibẹ lo jẹ ki n sọ fun un pe mo ti fun Safu naa ni nnkan.
Oun naa lo kọkọ beere. O ni ṣe mo mọ pe o yẹ ki n ṣe nnkan gidi fun Safu, mo si ṣalaye fun un pe owo ẹ to jẹ kọmiṣan to kan an ninu ọja ti a ta yẹn, owo nla ni, koda owo to to lati fi ralẹ lati tun ra mọto ni, Sẹki datọ mi, o ni oun ti mọ pe ọmọbinrin yẹn ko le pẹ ko too ṣoriire lọdọ mi. Mo ni mo sọ fun un pe ko ra mọto, ṣugbọn o loun ko ra, pe ile loun fẹẹ kọ, a si ti waa ra ilẹ kan si Mowe-Ibafo, pe wọn ti n lọọ ba a ja okuta si i. Sẹki si dide nilẹ tan bayii, bẹẹ lo kunlẹ fun mi, lo ba bẹrẹ si i ṣadura fun mi, pe bi mo ṣe n tun tawọn ẹni ẹlẹni ṣe, Ọlọrun yoo tun temi ṣe ju bẹẹ lọ.
Ohun ti mo fẹran ju lara Sẹki mi niyi, o fiwa naa jọ mi ki i ṣe kekere. Ko si nnkan oni-nnkan kan ti i jọ ọ loju. Bẹẹ ni ki ṣe ilara eeyan, bi ẹni kan ba ṣe ohun rere, inu rẹ yoo maa dun bii pe oun lo n ṣe e ni. Bo jẹ ẹlomi-in bẹẹ, yoo maa binu ni, bi ko ba tilẹ binu naa si gbangba. O le ni nijọ wo lọmọ naa de to ti n ra ilẹ, to fẹẹ maa kọle. Ṣugbọn ọrọ ye Sẹki gan-an, oun naa mọ pe bi ko ba jẹ Safu lo ta ọja naa, bo jẹ ẹlomi-in ni, bi n oo ṣe fun un ni ẹtọ to ba tọ si i naa niyẹn. Nitori ẹ ni inu ẹ ṣe dun to ti adura bọnu.
Mo ti fun Anti Sikira naa lowo. Sẹki tiẹ fajuro, o ni mi o gbọdọ ṣe bẹẹ, ṣugbọn mo sọ fun un pe ti a ba fẹẹ pẹ laye loootọ, to si fẹ ko daa fun wa dalẹ, afi ka ṣe bẹẹ fun awọn araale wa, nitori bi a ba lowo ti a ko ba fi mọ wọn, Ọlọrun naa yoo bi wa o. O ni Anti Sikira ki i ṣe eeyan daadaa ni, iyẹn ni oun ṣe n sọ bẹẹ, pe to ba jẹ eeyan daadaa ni, inu ko ni i maa bi oun. Mo ni ko si ohun to buru nibẹ, bi eeyan ba n ṣe aburu si wa, ti awa ba n ṣe daadaa si i, awa ko ni i gba ẹsan aburu, ẹsan daadaa ti a n ṣe ni a oo gba, bẹẹ ni aburu yoowu ti tọhun ba n ṣe ko ni i de ọdọ wa.
Awọn ọmọ aburo mi, iyẹn Ẹmu-Sii Olu-ọmọ, naa wa mi wa si ṣọọbu, wọn o ba mi o, Safu naa ni wọn ba. Ohun ti wọn sọ ya mi lẹnu, wọn ni awọn ti gbọ pe emi ni mo ra ile tuntun l’Oṣodi, awọn kan waa sọ fun mi pe ko si ewu kan fun mi ni o, awọn si ti ba gbogbo awọn ọmọ adugbo sọrọ, ko si ẹnikan to jẹ wa sibẹ ko waa daamu mi. Wọn fi nọmba meji silẹ, wọn ni ki Safu pe awọn ti ẹnibọdi ba wa to fẹẹ yọ iya awọn lẹnu. Nigba ti mo de ti wọn sọ fun mi, mo ni ki Safu tun pe wọn lori nọmba ti wọn fi silẹ, mo ni ko fun wọn ni owo ti wọn ba de, ka le mọ pe a ti yanju tọdọ wọn.
Haa, beeyan o ba ṣe bẹẹ yẹn, ko fi ti Kesari fun Kesari, lọjọ ti a ba fẹẹ ṣe nnkan kan mi-in ti wọn ba ya de, apa oluwa ẹ o ni i ka a, owo kekere gan-an le ma ka a. Bi wọn ṣe pọn mi le yẹn, ki emi naa yaa pọn wọn le lo daa. Safu ni nigba ti wọn wa toun fun wọn lowo, eyi ti wọn fi jo lọdọ mi niwaju ṣọọbu nibẹ, Safu lo ju wakati kan lọ, nitori oun funra oun ti ra bia fun wọn, ni wọn ba bẹrẹ si i ṣere nibẹ, awọn bii mẹẹẹdogun lo ni wọn wa. Nnkan ti mo fẹ niyẹn, nitori ko si ọmọọta adugbo kan to jẹ wa sibẹ ko wa daamu wa mọ.
Nibi ti a ti n ṣe eleyii ni Anti Sikira ti ko wahala ẹ de, eyi to si ko si yii, emi o mọ bi yoo ṣe bọ ninu ẹ, ko ma jẹ ohun ti yoo le e kuro nile ọkọ niyẹn. O ti waa ba mi pe ki n ba oun bẹ, ṣugbọn ẹbẹ iru wo ni mo fẹẹ bẹ ninu eyi to wa nilẹ yii, ọrọ to ti di ti awọn famili, ti awọn famili ni awọn n bọ wa sile wa ni Satide, ti mo si ti mọ pe ti ẹsẹ awọn famili ba fi pe le iyawo kan lori bẹẹ, afaimọ ko ma jẹ ohun ti yoo ba lọ niyẹn. Ariwo ti wọn n pa kiri Agege ni pe iyawo Alaaji kekere fẹẹ pa a. Awọn eeyan tiẹ kọkọ ro pe Safu ni, afi nigba ti wọn gbọ alaye pe ki i ṣe Safu, iyaale Safu ni.
Ohun to ṣẹlẹ ni pe lọjọ buruku ti ọrọ yii ṣẹlẹ, emi o si nile, emi ati Safu ti lọ si ṣọọbu ni tiwa. Ọrọ naa o tilẹ dun lẹnu mi, Iya Dele, Iyaale mi lo mọ gbogbo ẹ, nitori oju ẹ lo ṣe. Nigba ti a wa ni ṣọọbu ti mo ri i to bọ silẹ lori ọkada, mo ti mọ pe nnkan buruku kan lo ṣẹlẹ. Akọkọ ni pe Iya Dele ki i gun ọkada, bo si ti de yii, nnkan kan ṣẹlẹ ni, nitori ko tun mura daadaa, ko si jọ pe o ti i wẹ. Bo ṣe bọ silẹ lo ti n pariwo, ‘Alaaja!, Alaaja! tete maa bọ nile o! Wọn ti fẹẹ ṣe baba ẹ leṣe o, emi o si nibẹ o!’ Nigba to ti n sọ bẹẹ ni mo ti mọ pe nnkan kan ti ṣẹlẹ.
Iya Dele ki i deede pe mi ni Alaaja, afi ti a ba wa nita, tabi ti ọrọ kan ba wa to ka a lara gidi ti ki i ṣe ọrọ ere rara. Bo si ti bẹrẹ si i lọgun Alaaja, bẹẹ ni mo ṣe sare pade ẹ, ti mo ni ko jẹ ka wọle kia. Safu tadi mẹyin, ki i fẹẹ da si ọrọ wa. Funra iyaale mi naa lo pe e pe ṣe oun naa ko ni i maa bọ ko waa gbọ ohun to ṣẹlẹ. N lawọn mejeeji ba wọ inu ọọfiisi. Eke buruku ni Abbey, iyẹn iyawo Dele, nigba to ti ri iya ọkọ ẹ lo ti n gbawaju, to n gbẹyin, o fẹẹ mọ ohun to ṣẹlẹ, ṣugbọn igba to ti ri oju mi lo ti sare jade, o pada si ṣọọbu kia. Ni Iya Dele ba ni nnkan ti ṣẹlẹ nile o.
O ni obinrin kan lo wale pẹlu ọlọpaa meji o, lo ba ni Alaaji loun beere, nigba ti Alaaji jade to ri ọlọpaa meji, o ni kobinrin naa jẹ ki awọn wọle, ṣugbọn niṣe lobinrin naa ta ku, lo ba bẹrẹ si i pariwo, to n sọrọ fatafata. Nibẹ loun ti sare jade. O ni nigba ti oun jade loun ri obinrin naa, ariwo to si n pa ni pe ‘Nibo ni Sikira wa! Nibo ni aṣẹwo yẹn wa! Ẹ pe e ko jade si mi o!’ Wọn lo sọ pe ọkọ oun n ba Anti Sikira sun, eyi to buru ni pe ninu ile oun ni wọn ti n ṣe e, nibẹ loun ti ka wọn mọ, ni Anti Sikira ba sa lọ! Pe to ba jọ bii irọ, panti to wọ ti ko le duro mu loun mu wa yii o! Iya Dele ni loootọ loootọ, panti Anti Sikira lobinrin yẹn na soke o!