Taofeek Surdiq, Ado-Ekiti
Titi digba ti igbẹjọ yoo tun waye lori ẹsun ifipa ba ọmọ bibi inu rẹ lo pọ ti kootu fi kan an, ọkunrin kan, Emmanuel Bejide, yoo ni lati wa lọgba ẹwọn l’Ekiti na, gẹgẹ bi Adajọ Mojisọla Salau ṣe paṣẹ.
Ọsẹ to kọja yii ni wọn foju Bejide ba kootu kan l’Ado-Ekiti, agbefọba Sọdiq Adeniyi si ṣalaye pe ko ti i pẹ rara ti olujẹjọ yii de lati orilẹ-ede Malaysia.
O ni ilu naa lo fi n tan ọmọ rẹ obinrin, ọmọ ọdun mẹtadinlogun, pe oun yoo mu un lọ boun ba ti n pada sibẹ, ohun to si fi n ba a lo pọ pẹlu bi ibalopọ naa ko ṣe tẹ ọmọ naa lọrun to niyẹn.
Agbefọba ṣalaye pe kilaasi to gbẹyin ni ọmọ Bejide wa nileewe girama kan Ikẹrẹ-Ekiti. O ni ọmọ naa sọ pe oṣu keji rẹ ti baba oun ti Malaysia de, nigba to si ti de lo ti n mu oun lọ sawọn otẹẹli kaakiri Ado-Ekiti ati Akurẹ, to n ba oun sun nibẹ pẹlu ileri pe awọn yoo jọ pada si Malaysia ni.
Eyi to ṣe lọjọ kẹẹẹdogun, oṣu kẹjọ to pari yii, ni aṣiri fi tu gẹgẹ bi agbefọba ṣe wi, to fi di pe ọwọ ọlọpaa tẹ ẹ, to si pada dele-ẹjọ.
Nigba to n gbe idajọ rẹ kalẹ, Adajọ Mojisọla Salau paṣẹ pe ki wọn lọọ fi Emmanuel Bejide pamọ sọgba ẹwọn titi di ọjọ kẹrindinlọgbọn oṣu kẹsan-an yii ti igbẹjọ yoo maa tẹsiwaju.