Jọkẹ Amọri
Olori ijọ Methodist ilẹ wa nigba kan, Biṣọọbu Ayọ Ladigbolu, naa ti fifẹ han lati dupo Alaafin ilu Ọyọ to ṣi silẹ bayii, latari Ọba Adeyẹmi to waja.
Ninu ọrọ ti baba agbagbalagba ẹni ọdun mẹtalelọgọrin toun naa mọ aṣa ati iṣe Yoruba dunju dunju yii ba akọroyin Punch sọ lo ti sọ pe loootọ ni orukọ oun wa ninu awọn ti yoo du ipo naa, ṣugbọn oun ko ni i wi ohunkohun nipa rẹ bayii.
Baba naa fidi rẹ mulẹ pe idile Agunloye ni yoo fa ọmọ oye kalẹ, ninu idile naa ni baba yii si ti wa.
Baba Ladigbolu ni, ‘‘Mọlẹbi Agunloye ni mo ti wa, mo si jẹ ọmọ Ladigbolu ninu ẹka kan ninu idile Agunloye, Asiko tiwa niyi, ẹtọ wa si ni labẹ ofin lasiko yii, ṣugbọn a n woju Oluwa.
‘‘Ṣugbọn a n ṣọfọ lọwọ lasiko yii, koda bi ẹnikẹni ba tilẹ ni ifẹ si ipo naa, yoo ni lati ṣe suuru ni titi ti asiko ti a n ṣọfọ yoo fi pari ko too fi ipinnu rẹ han.’’
Baba agbalagba to sun mọ Alaafin Adeyẹmi pẹkipẹki nigba to wa laye naa kọ lati dahun nigba ti wọn bi i leere boya eyikeyii ninu awọn ọmọ rẹ nifẹẹ si ipo naa.
Ni bayii, eeyan bii mẹẹẹdọgbọn lo ti fi ifẹ han lati du oye Alaafin.