Bi APC ṣe fa Musulumi kalẹ funpo aarẹ atigbakeji fihan pe ẹsin wa lọga- Auwal

Faith Adebọla

Oniwaasi ẹsin Musulumi kan, Abdulmutallab Mohammed Auwal, ti parọwa sawon ẹlẹsin Musulumi jake-jado Naijiria lati ṣugbaa ẹgbẹ oṣelu All Progressives Congress, APC, ati oludije funpo aarẹ wọn, Aṣiwaju Bọla Ahmed Tinubu, ninu eto idibo gbogbogboo to n bọ, o ni bi ẹgbẹ oṣelu naa ṣe fa ẹlẹsin Musulumi kan naa kalẹ funpo aarẹ ati igbakeji dara gan-an, o fihan pe ẹsin Musulumi lọba awọn ẹsin yooku, oun si ni olubori. Nitori bẹẹ, ko sohun to tọna ju kawọn Musulumi ja fitafita ni gbogbo ọna lati ri i pe ẹsin naa moke, kawọn oludije ọhun si moke pẹlu rẹ lasiko ibo lọ.

Auwal ni ni tododo, ko tun si ẹsin to daa to ẹsin Musulumi, igbesẹ ti APC si gbe yii, igbesẹ to bọla fun ẹsin naa ni, afi kawọn olusin tori eyi bu ọla fawọn oludije ẹgbẹ naa nipo aarẹ ati igbakeji.

Ilu Kano, nibi eto adura pataki tawọn alaafaa atawọn olukọ ẹsin Musulumi pesẹ si, titi kan Gomina ipinlẹ Kano, Abdullahi Ganduje, eyi ti wọn ṣeto rẹ lati ṣatilẹyin fun ipolongo ibo Tinubu ati Shettima, lọrọ naa ti waye lọjọ Ẹti, Furaidee, ọjọ karun-un, oṣu Ki-in-ni, ọdun yii.

Oniwaasi Auwal ni: “Pataki apejọ wa oni ni lati jẹ kawọn agbaagba ẹsin Musulumi, ati gbogbo ẹlẹsin naa mọ pe tikẹẹti ẹlẹsin kan naa meji ti APC fa kalẹ funpo aarẹ ati igbakeji ki i ṣe lati le mu eto iṣejọba rere wa lasan o, ki i ṣe tori ki wọn le pese ọna tabi nnkan amayedẹrun nikan o, o jẹ lati fihan pe gbọgbọrọ tọwọ n yọ ju ori ni ẹsin wa fi tayọ awọn ẹsin yooku, oun si lọba gbogbo ẹsin. Tikẹẹti yii bu ọla fun ẹsin Musulumi ni, tori ẹ, afi kawa naa fi ibo wa bu ọla fun un.

“Lafikun, ṣebi ẹ mọ pe Musulumi san ju keferi lọ. Ti Musulumi ba waa di meji nkọ? Idi ta a fi ṣeto apero yii niyẹn, ka le mọ pe Musulumi meji ti wọn fa kalẹ yii jẹ ipe fun wa lati ṣatilẹyin fun wọn,  ka gbeja wọn.”

Olukọ ẹsin Musulumi mi-in, to jẹ adari awọn Izala ni Kano, Sheikh Abdallah Saleh Pakistan, sọ pe o ti pẹ ti Tinubu ti n ṣagbatẹru iyansipo Musulumi meji sipo aṣẹ.

“Tipẹtipẹ ni Tinubu ti n lakaka ki Musulumi meji le wa nipo apaṣẹ Naijiria. Ṣe ẹ ranti pe oun lo fa Nuhu Ribadu kalẹ pẹlu ẹlẹsin Musulumi to jẹ Yoruba nigba kan, oun naa lo si ṣatilẹyin fun tikẹẹti MKO Abiọla ati Babagana Kingibe tawọn mejeeji jẹ ẹlẹsin Musulumi” gẹgẹ bo ṣe wi.

Gomina ipinlẹ Kaduna, Ganduje, ninu ọrọ tirẹ sọ pe awọn Musulumi maa ṣatilẹyin fun Tinubu ati Shettima, o lọrọ fifa ẹlẹsin kan naa kalẹ ki i ṣe tuntun ni Naijiria, Abiọla ati Kingibe ṣe e, wọn si jawe olubori, ba a ba yọwọ bawọn ologun ṣe da ibo naa nu. O ni ti ọtẹ yii naa maa yege.

Leave a Reply