Bi ijọba Buhari ba ro pe mimu Sunday Igboho yoo dẹruba wa, wọn n ṣere ni-Imaamu Yoruba n’Ilọrin

Faith Adebola

Imaamu Yoruba niluu Ilọrin, Sheik Abdulraheem Aduranigba, ti sọ pe ọrọ ijọba Naijiria ti wọn lọọ mu Sunday lorileede Benin da bii ẹni ti ara n ni. O ni ọrọ wọn da bii iyawo to fẹẹ lọ nile ọkọ, ṣugbọn ti ọkọ ko fẹ ko lọ. O ni gbogbo ọna to ba mọ pata ni yoo gba lati kuro nile iru ọkọ bẹẹ.

O ṣalaye fun ALAROYE lọjọ Iṣẹgun, Tusidee, ọsẹ yii, pe Boko Haram wa nilẹ wa to yẹ ki awọn eeyan naa dojukọ, wọn ko de ọdọ wọn, awọn afẹmiṣofo wa nibẹ, wọn ko mu wọn, Igboho to n ja fun ẹtọ awọn eeyan ilu rẹ ni wọn n wa kiri lati mu. O ni igbesẹ naa ko bojumu.

Ọkunrin yii fi kun un pe wọn ro pe ti awọn ba mu Igboho, ara awọn to n jijagbara fun Yoruba yoo rọ, tabi pe ẹru yoo ba wọn, wọn n ṣere ni. Wọn ko mọ pe eyi gan-an ni yoo tun mu awọn ṣiṣẹ ju bi awọn ti n ṣe e tẹlẹ lọ, ti yoo si mu ki awọn eeyan to n ṣe ijangbara pọ si i. Aduranigba ni bi Igboho ko ba tilẹ si ni aarin awọn, fungba diẹ ni, ati pe eyi ko di ijangbara bibeere fun ominira Yoruba lọwọ. O ni iṣẹ naa n tẹsiwaju ni.

‘’Ti wahala ijinigbe, irẹnijẹ ati ijẹgaba ko ba dopin, ti awọn ẹya kan si ni awọn ko ṣe mọ, awọn fẹẹ maa lọ, ẹṣẹ wo lo wa ninu eleyii. Sunday Igboho ni iya ti wọn fi n jẹ awọn eeyan oun ti to, o ni ki wọn yee pa wọn, ki wọn yee ba nnkan oko wọn jẹ, ki wọn si yee fipa ba awọn aburo ati ẹgbọn awọn sun. Ki waa ni ohun to ṣe to lodi ninu eleyii. Ara n kan ijọba Naijiria ni, wọn ti mọ pe ọrọ naa ti fẹẹ bọwọ sori ni wọn fi n wa gbogbo ọna lati mu Sunday Igboho, pe boya eleyii yoo pa awọn eeyan lẹnu mọ. Ṣugbọn iṣẹ ṣẹṣẹ bẹrẹ ni gẹgẹ bo ṣe sọ.

 

Leave a Reply