Adefunkẹ Adebiyi, Abẹokuta
“Beeyan ba yan aṣọ rira ati riran lodi nitori aisowo, o daju pe ko ni i yan ohun ti yoo jẹ lodi. Paapaa, nnkan isebẹ olowo pọọku bii iru ti mo n ta yii, mo mọ pe ma a ta ti mo ba gbegba ẹ, iṣẹ iya mi dẹ tun ni, ohun to jẹ ki n maa ta a niyẹn lati ọdun keje sẹyin”
Baale ile kan torukọ ẹ n jẹ Lukman Akanji lo sọrọ yii lọja Adatan, niluu Abẹokuta, iyẹn lọjọ Ẹti, Furaidee, to kọja yii. Lasiko ti ALAROYE n fọrọ wa awọn ọlọja lẹnu wo lori ẹkunwo buruku to n gun ori awọn ọja lasiko yii la ṣalabapade ẹ. O si ṣalaye siwaju si i lori idi to fi n ṣe iru funra ẹ, to tun n gbe e waa ta lai wo ti pe iṣẹ obinrin ni. Lukman sọ pe,
“ Mo n ta iru lọja Adatan nitori ko si nnkan kan ni Naijiria yii mọ, mo si maa jẹun. Mo kọṣẹ telọ, mo ṣe firidọọmu, mi o riṣẹ ṣe. Iṣẹ ọhun ko lọ deede, mi o dẹ fẹe ya ọmọ ita kalẹ, mi o fẹẹ huwa ti ko daa ni mo ṣe jokoo ti mo ro o pe kin ni mo le fi aye mi ṣe. Bi mo ṣe ronu kan iṣẹ iru yii niyẹn.
“ Iru ni mama mi n ta, Iyana Mortuary ni wọn ti n ta tiwọn, l’Abẹokuta yii naa ni. Mo ti mọ bi wọn ṣe n ṣe e tẹlẹ, a maa ra iyere, a maa se e, to ba to asiko, a maa gbe e lọ sodo, a maa fọ ọ, a maa fi eroja to ba yẹ si i, a dẹ maa gbe e wa sọja lati ta, o dowo naa niyẹn.
“Latigba ti mo dẹ ti bẹrẹ si i ta iru yii ni mo ti ri iyatọ daadaa ninu aye mi, mo ti fẹyawo nidii ẹ, ọdun keje ree. Mo n gbọ bukaata to yẹ ki n gbọ gẹgẹ bii baale, ko dẹ si wahala to kọja agbara mi.
‘‘Ilu ti ko daa lo jẹ ki n maa ta iru, ṣugbọn nnkan kan naa lo maa gbe eeyan debi kan. Mi o le fi iṣẹ iru ṣiṣẹ yii silẹ mọ o, oun ni ma a maa ṣe lọ, nitori o pe mi. Oju o ti mi nidii ẹ ri, pe boya nitori obinrin lo n ta iru, ti emi si jẹ ọkunrin.
“Emi tiẹ tun maa n ta ju awọn obinrin lọ, nitori o maa n jọ ọpọlọpọ eeyan loju pe ọkunrin lo n po iru pọ, to n pọn ọn si lailọọnu yii, awọn obinrin dẹ lo pọ ju ninu onibaara mi, pẹlu ọyaya ni wọn maa n fi ba mi raja, nitori nnkan to jọ wọn loju ni mo n ṣe.’’
Nipa amọran ti Lukman le gba awọn eeyan ti ko niṣẹ lọwọ, o ni ki wọn ma tiju iṣẹ kan lati ṣe, nitori ẹni to ba jale nikan lo ba ọmọ jẹ.
O fi kun un pe awọn iṣẹ ajogunba tawọn eeyan maa n foju tẹnbẹlu lo maa n jawo ju, to si maa pe gan-an fẹni ti ko ba tiju. Eyi si san ju ole jija, ijinigbe tabi fifeeyan ṣowo lọ.