Eyi ti mo fẹẹ sọ yii ki i ṣe wọn ni wọn pe o, ohun to ṣoju iru awa yii daadaa ni. Iyẹn nipa wahala ti mo n ṣalaye ẹ lọsẹ to kọja, ọro ogun wẹẹti-ẹ ti mo mẹnu ba wẹrẹ, oju temi yii lo ṣe o. Ijọba awọn Hausa yii naa ni, bi gbogbo nnkan si ṣe n lọ lasiko yii naa lo ri nigba ti mo n sọ yii. Tafawa Balewa lolori ijọba, Nnamdi Azikiwe ni olori Naijiria, oun lo yẹ ko je ọga fun Balewa, bi nnkan ba lọ bo ti yẹ ko lọ. Ṣugbọn Sardauna Sokoto, iyẹn Ahmadu Bello, ni olori ẹgbẹ awọn Balewa, eyi ja si pe oun ni ọga fun Balewa to n ṣejọba, ohun ti oun ba fẹ ni Balewa n ṣe, ki i ṣe eyi ti Azikiwe ba fẹ. Gbogbo ohun to wa lọkan Sardauna yii ko ju bi Hausa-Fulani yoo ṣe di olori fun Naijiria pata lọ. Iyẹn ni mo ṣe sọ pe bi ọrọ wa ṣe ri nigba naa lo tun n ri lọ yii o.
Nnkan le mọ Yoruba lara. Emi yii si wa lara awọn ti wọn n tẹle Awolọwọ ati Akintọla, lati ileewe la ti n ba wọn ṣe. Ṣugbọn nigbai ti ọrọ Yoruba fẹẹ dojuru pata, Sardauna ati Ladoke Akintọla to jẹ olori ijọba wa di ọrẹ nla. Kia ni ija ti de, nitori awọn Sardauna fi ọgbọn fa Akintọla mọra ni. Akintọla bẹre si i gun baba wa garagara, o gba agbara kun agbara lọwọ awọn Sardauan, o fi ara ẹ joye olori Yoruba ni apapandodo. Nibi ti inu bi wa de, bii ka da ina nla ka sọ Akintọla yii si ni. Ṣugbọn pẹlu iranlọwọ oun Akintọla yii, awọn Sardauna sọ Awolọwọ sẹwọn, gbogbo agbara oṣẹlu ilẹ Yoruba si wa lọwọ Akintọla. Kinni naa o tẹ wa lọrun rara, ṣugbọn ki la fẹẹ ṣe. A kan n woran ni.
Ṣugbọn ipakọ ko gbọ ṣuti, ori ẹlẹgan lo bajẹ ni Akintọla n fi ọrọ naa ṣe, lojopjumọ lawọn ọmọ wọn n bu wa, gẹgẹ bi awọn oloṣelu wa asiko yii naa ni o. Akintọla gbagbọ pe ko sohun ti ẹnikẹni fẹẹ fi oun ṣe, ati pe ohun yoowu ti oun ba ṣe nigba naa, aṣegbe ni. Ko si ohun ti a le fi i ṣe loootọ, o ti gba gbogbo agbara lọwọ wa. Inu to n bi wa yii, a ti ro pe bi asiko ibo ba de, a maa fi ibo le e lọ ni, a ti leri pe ẹni yoowu ti Akintọla ba wa lẹyin ẹ, awa o ni i dibo fun un. A o mọ pe agbara Akintọla pọ to bẹẹ yẹn, gbogbo eto idibo naa ko ri bi a ṣe ro o si, awọn eeyan Akintọla lo wọle, ohun ti a si foju ri ko ṣee maa fẹnu sọ. Ni 1964 yii, ẹ wo o, inu bi wa, ṣugbọn ko sohun ta a le ṣe. Awọn Sardauna ati Akintọla da ọlọpaa sigboro, ẹni it wọn ba si ri mu ninu wa, ẹwọn ni, nitori adaluru ni wọn n pe wa.
1965 lo ku ti a n reti, ibo awọn Akintọla gan-an niyẹn, ibo to fẹẹ fi wọle ẹẹkeji ni. Bi ibo ta a di lakọọkọ ṣe ri, bẹẹ ni ti 1965 yii naa ri, koda, ti 1965 ti mo n sọ yii tiẹ buru debii pe awọn ti o dije rara, orukọ ẹlomi-in n jade pe oun lo wọle. Awọn eeyan tiwa to dije ti wọn si wọle, orukọ wọn o jade ninu iwe awọn ti wọn ṣeto idibo.
Nigba ta a dibo tan, ibinu wa waa le si, n la ba bẹrẹ iwọde pe eru ni eto idibo ti wọn ṣe, aa si fẹ Akintọla ni olori ijọba wa. Iwọde la ṣe titi to fi di nnkan mi-in, iwọde yii la ṣe to fi di wahala nla gan-an. Nibi ti aya mi ti n ja fun ti eyi ti a n ṣe lọwọ yii niyi, nitori eyi ti mo n sọ yii ṣoju emi o. Ṣe ẹ ri i, nigba ti iwọde ba bẹrẹ, awọn eeyan ti ọrọ dun, awọn eeyan ti wọn mọ ohun to ṣẹlẹ gan-an, ti wọn si n fẹ ayipada ẹ, awọn ni wọn maa n ṣaaju, wọn si le fi ọjọ meji mẹta ṣe e ko too di pe kakuku gba ile ẹ jokoo, niwọnba igba ti wọn ba ti ri i tawọn ijọba ti n lakaka lati ṣe ohun ti wọn n beere fun. Iru ẹ lawa ṣe ni tiwa.
Ṣugbọn ọrọ iwọde ki i bẹrẹ bẹẹ ko pari bẹẹ, paapaa to ba jẹ iwọde ti awọn oloṣẹlu. Ohun to kọkọ maa n ṣẹlẹ ni pe awọn onijangbọn naa aa jade, bo tilẹ jẹ ko si eyi to kan wọn pẹlu iwọde naa. Ṣugbọn tiwọn dara. Awọn ti tiwọn buru lawọn ọdaran, awọn ọmọọta, ati awọn ti wọn wa niluu ti wọn o niṣẹ, ti wọn o si ri nnkan ṣe. Awọn yii lo buru ju, nitori bi iwọde gidi ba tan, iwọde tiwọn o ni i tan, awọn aa lo anfani naa lati jale, lati kole, ati lati fiya jẹ awọn oloṣẹlu ati ọlọla ti wọn ti mọ tẹlẹ, agaga awọn ti wọn ba sọ pe wọn o ba mẹkunnu ṣe, ti wọn o si n fun mekunnu ni nnkan.
Bi wọn ti n kuro nile oloṣelu kan ni wọn aa maa lọ sile oloṣelu mi-in, tabi to jẹ bi wọn ti n kuro nile olowo kan ni wọn aa maa lọ sile olowo mi-in, ti wọn aa si maa ko wọn ni nnkan. Awọn naa ni wọn maa n pa awọn oloṣelu tabi olowo mi-in ti wọn ba ri. Bi awọn ti wọn ko niṣẹ lọwọ ba ṣe pọ ni adugbo kan to, bẹẹ lawọn janduku ọjọ naa yoo ṣe to. Bi awọn ọmọọta adugbo kan ba ti pọ to, bẹe lawọn ti wọn aa maa dana sunle ati dukia aa ṣe pọ to. Bi idaamu, ikowojẹ ati iwa ibajẹ awọn oloṣelu ati olori ijọba ba ṣe pọ to, bẹẹ ni ibinu awọn ti wọn n yide yii yoo ṣe maa pọ si i, wọn aa si ṣe bẹẹ titi ti wọn aa fi ba nnkan jẹ kọja atunṣe.
Ibo ti mo n sọ pe a di ni 1965 yii, lẹyin ti ibo ti di wahala tan, awọn ọmọọta gba gbogbo oju popo, wọn n da gbogbo mọto lọna, wọn n gbowo, wọn si n fiya jẹ ọlọpaa tabi oloṣẹlu ti wọn ba ri. Awa ti a bẹrẹ ija yii gan-an ti wa nile wa o, a ko si ninu awọn onijaadi yii rara. Awọn mi-in ko lọ soju ọna, tabi titi kan, ojule si ojule lawọn n tọ kiri. Ile awọn oloṣelu ta a ti sọ fun wọn pe iwa wọn ko daa, tabi ta a ti pariwo pe wọn kowo jẹ, ni wọn n lọ. Oloṣelu ti eṣu ba ṣe, ti wọn jaja ri mu, wọn maa n da bẹntiroolu si wọn latori delẹ ni, wọn aa fi bẹntiroolu wẹ ẹ, nnkan ti wọn n pe ni wẹẹti-ẹ niyẹn. Bi wọn ba ti fi wẹ ẹ bayii, wọn aa ṣana si i ni. Tọhun yoo jona ku ni. Bi ogun wẹẹti-ẹ ṣe fẹju niyẹn.
Awa oloṣelu tinu bi ti wọle o, ṣugbọn awọn janduku, ọmọọta ati araalu ko wọle mọ, wọn ti sọ kinni naa di ounjẹ, wọn ti sọ ọ di iṣẹ oojọ: wọn ko roko, wọn ko yẹna mọ, ohun to ku ti wọn ṣe niyẹn. Paripari rẹ waa ni pe ko si ilu kan tabi ileto kan, bo ti wu ki ibẹ kere to ti ogun yii ko de ni ilẹ Yoruba, bẹẹ o ti kuro ni ogun awọn oloṣẹlu, nitori apa awọn oloṣelu paapaa ko ka a mọ, awọn ọdaran yii kan fi ọrọ Awolọwọ ati ti ọta ẹgbẹ Dẹmọ kẹwọ ni, awọn to ku to n ja ija yi, awọn ọmọọta atawọn ti wọn ko niṣẹ ati araalu ti inu to n bi wọn ju tiwa lọ lo ku nidii ẹ. Igba ti wọn o kuku ni iṣẹ gidi kan lọwọ tẹlẹ, ko jẹ ki ogun naa tan. Wọn ko ni ibi ti wọn n lọ, nibi ti wọn ba ti de ti wọn ri ounjẹ ni wọn ti n jẹun, ti wọn ba si ti jẹun tan, wọn aa tun ko si wahala wọn ni. Bi wọn ṣe ṣe ti oṣu kin-in-ni pari, ti oṣu keji tẹle e niyẹn.
Ki i ṣe pe awọn ọlọpaa o gbiyanju, wọn ṣe titi apa wọn ko ka a ni. Bi araalu tabi awọn janduku ba gba igboro, ki i ṣe awọn ọlọpaa lo le le wọn wọle. Bo ṣe ri ni 1965 yii ree, wahala naa si ni wọn fa titi ti awọn ṣọja fi fibinu gbajọba lẹyin oṣu kẹta ti wọn ti n dana sunle, ti wọn n dana sun awọn eeyan, ti ohun ti ọpọlọpọ awọn oloṣelu wa fi eru ko jọ ti jona loju wọn. Bi awọn ṣọja ti gbajọba ni ọrọ tun dija laarin awọn naa, nitori ogun ẹleyamẹya ti awọn onibajẹ oloṣelu ti da silẹ, ija to si ṣẹlẹ laarin awọn ṣọja yii ko pari, ogun abẹle lo da nitori wọn fẹẹ fi agbara han ara wọn. Bii miliọnu meji ọmọ Naijiria lo ku si ogun ti wọn fi ọdun mẹta ja yii, bi iru ẹ ba si ṣẹlẹ lasiko yii, iye miliọnu eeyan to maa ba kinni naa lọ, afi ki Ọlọrun ma jẹ ka ri i. Bẹẹ ilu ko fara rọ, gbogbo ohun to ṣẹlẹ ni 1964 si 1965, to ṣoju awa yii, naa lo tun n ṣẹlẹ yii o.
Awọn oloṣelu ni wọn maa n da a silẹ, paapaa awọn oloṣelu ti wọn ba gbabọde fun Yoruba, lọdọ wọn ni kinni naa ti n bẹrẹ ko too di ohun to kari ilu yikayika. O ti tun n bẹrẹ bayii o. Ki Ọlọrun ma jẹ ki awa ọmọ Naijiria tun foju wina ogun. Mo tun n fi asiko ti mo ni yii kilọ fawọn oloṣelu Yoruba ki wọn ṣọra wọn, igbẹyin rogbodiyan tabi ijaagboro ki i daa fun wọn o, gbogbo ohun ti wọn ba ko jọ ni yoo bajẹ pata loju wọn.