Faith Adebọla, Eko
Minisita feto igbokegbodo ọkọ ofurufu nigba kan, Fẹmi Fani-Kayọde, ti bẹnu atẹ lu iṣẹlẹ ipakupa to waye lopin ọsẹ to kọja, nigba tawọn agbebọn kan lọọ rẹbuu awọn arinrin-ajo lọna marosẹ ilu Jos, nipinlẹ Plateau, ti wọn si da ẹmi eeyan mejilelogun legbodo, ti ọpọlọpọ tun fara pa yannayanna. Fẹmi ni o ya oun lẹnu pe iwa ẹranko bẹẹ ṣi le maa waye lorileede yii, o lo yẹ kawọn eeyan ti ṣiwọ ninu iwa ẹranko.
Ninu ọrọ to kọ sori ikanni abẹyẹfo (tuita) rẹ lọwurọ ọjọ Aje, Mọnde yii, Fani-Kayọde ni: “Awọn kan si lọọ rẹbuu awọn alaimọwọ-mẹsẹ ẹlẹsin Musulumi ti wọn n ṣẹri rele wọn jẹẹjẹ lati ibi ti wọn ti lọọ jọsin f’Ọlọrun, wọn si ki wọn mọlẹ, wọn dumbu wọn bii ẹran Ileya, lori ẹsun pe wọn fẹẹ gbẹsan bawọn kan ṣe pa awọn ẹlẹsin Kristẹni ẹlẹgbẹ wọn ṣaaju akoko yii. Ibeere mi ni pe, ṣe awọn ti wọn pa yii wa lara awọn to huwa laabi tiṣaaju ni. Ṣe fifi oro ya oro maa jẹ ki oro kaṣẹ nilẹ ni. Ṣe ara iwa ati ilana ẹsin Kristiẹni ni lati lugọ de ẹni ti ko ṣẹ wọn, ti ko si halẹ mọ wọn, ki wọn si lawọn fẹẹ gbẹṣan lara wọn fun nnkan to ti waye tẹlẹ?
O ti pẹ ti mo ti n sọrọ lori bawọn ẹlẹsin Musulumi kan ṣe maa n doju sọ awọn ẹlẹsin Kristẹni, lati pa wọn nipakupa, mi o si le tori pe mo jẹ Kristẹni, ki n waa dakẹ nigba tawọn kan ba lawọn n gbẹsan, tori ẹ lawọn ṣe lọọ fẹmi awọn yii ṣofo. Ṣe ẹjẹ kan naa kọ lo wa lara gbogbo wa ni.
Iwa buburu jai lohun to ṣẹlẹ yii, iwa ẹranko ni, o si yẹ ka ti jawọ ninu iwa ẹranko lorileede yii, ka huwa to ba teeyan gidi mu. O yẹ ka ṣiwọ pipa ara wa bii ẹni pa eera.
Tiru nnkan bayii ba n lọ bẹẹ, lọjọ kan la maa ji, a o si ni i ri orileede yii mọ, ohun to maa ṣẹku ni ajoku ile ati dukia, ọpọ ninu wa yoo ti lọ, tabi ka ti dero ogunlende alarinkiri nibomi-in ta a ba sa lọ.
Ko sẹni to le ṣẹgun ogun ẹsin tabi ti ẹya niru orileede to kun fun ẹya ati ẹsin ati aṣa loriṣiiriṣii bii tiwa yii. Ọlọrun o ni i jẹ kiru ẹ ṣẹlẹ o, ṣugbọn to ba waye, pẹlu bi nnkan ṣe n lọ yii, gbogbo wa la maa jiya rẹ, gbogbo wa la maa geka abamọ jẹ.
Mo rọ wa pe ka simẹdọ wayi, ka jogun-o-mi.